Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni ẹgbẹ awọn Dokita to n tọju ẹranko nilẹ yii, (Nigerian Veterinary Medical Association), ẹka ti ipinlẹ Kwara, kede fun ijọba pe awọn arun ẹranko ti gbode bayii, to si lewu fun eto ilera ati ọrọ aje ipinlẹ naa.
Alaga ẹgbẹ ọhun, Dokita Saka Shittu, lo kede ọrọ naa nibi atẹjade kan to fi lede niluu Ilọrin. Ninu ọrọ rẹ, o ni awọn ẹranko ti awọn arun naa n sakọlu si ni ohun ọsin bii, aja, ehoro, aguntan, ewurẹ ati ohun ọsin nla bii maaluu. Nigba to n sọrọ nipa ewu ti arun naa le da silẹ, Shittu ni o le sokunfa ki ounjẹ wọn, bakan naa lo le ko ba eto ọrọ-aje awọn agbẹ ati ijọba.
O tẹsiwaju pe lati bii ọṣẹ meloo kan ati oṣu diẹ sẹyin, ọpọ agbẹ ati Fulani darandaran lo ti padanu ohun ọsin wọn ṣọwọ awọn arun buruku ọhun, ti iwadii si fi han pe arun kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Haemorrhagic, ti ṣeku pa ehoro bii ẹgbẹrun mẹwaa niye, to si ṣakoba fun agbẹ bii ọgọrun-un kan, to si jẹ pe ninu oṣu Kejila, ọdun to kọja, ni wọn kọkọ sawari arun naa nipinlẹ Kwara, ati orile-ede Naijiria lapapọ.
Siwaju si i, alaga tun salaye pe arun kan ti orukọ rẹ n jẹ Pestes de Petite Ruminates (PPR), ti ran ewurẹ ati aguntan to to ẹgbẹrun meji, lọ sọrun, ti arun leptospirosis si n yọ awọn aja lẹnu, ati pe arun leptospirosis yii ni o n kọ ẹgbẹ naa lominu nitori aisan naa le ran eniyan latara ẹranko, ilera araalu si jẹ ẹgbẹ naa logun.
Wọn ti waa rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati tete gbe igbeṣẹ pipinwọ arun ọhun, ki nnkan too bajẹ jinna, ki ijọba peṣe awọn irinṣẹ fun awọn dokita naa lati tete gbogun ti aru yii.