Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Bi eto idibo gomina to fẹẹ waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, ṣe n sunmọle ni ina wahala to n ja ran-in ran-in laarin ẹgbẹ oṣelu All Progressive Party (APC) to n ṣe ijọba lọwọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) to jẹ ẹgbẹ alatako tubọ n burẹkẹ si i lori ọkan-o-jọkan awọn ẹsun ti wọn n fi kan ara wọn.
Latigba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ti gba eeku ida iṣakoso mọ ẹgbẹ Peoples Democratic Party to n ṣe ijọba tẹlẹ nipinlẹ Edo lọwọ lawọn ọmọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo ti n pariwo, ti wọn si n kegbajare pe nnkan ko ni i fara rọ rara ti awọn aṣaaju APC ba fi gbiyanju lati lo ete oun iwa ojooro kan naa ti wọn fi gba ipinlẹ Edo, ninu eto idibo to n bọ nipinlẹ Ondo.
Ohun ti Alaaji Abdullahi Ganduje to jẹ alaga gbogbogboo fẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lorilẹ-ede yii si tun fi bọrọ jẹ patapata ni ti ẹnu to n fọn lẹyin ti ajọ eleto idibo kede Sẹnetọ Monday Okpebholo gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa pe ẹgbẹ APC ti ṣeto abẹlẹ ti awọn tun fẹẹ fi gba awọn ipinlẹ bii Ondo, Ọṣun ati Ọyọ mọ awọn PDP lọwọ.
Awọn aṣaaju ẹgbẹ PDP naa ko si jẹ kọrọ yii tutu ti wọn fi fun ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Kano naa lesi pe awọn naa ti n duro de oun ati igbimọ rẹ lori itukitu tí wọn le maa mura lati pa ninu eto idibo gomina to n bọ nipinlẹ Ondo, ati pe nigba yii ni yoo too mọ iyatọ to wa laarin ipinlẹ Ondo ati Edo.
Afaimọ ko ma jẹ ohun tawọn asaaju PDP ri ree ti wọn fi n fapa janu, ti wọn si n fẹhonu han lori ẹni ti ajọ eleto idibo gbe wa sipinlẹ Ondo gẹgẹ bii aṣoju wọn, iyẹn Abilekọ Oluwatoyin Babalọla.
Ìgbàgbọ́ wọn ni pe, ko ni i ṣee ṣe fun ẹgbẹ kankan lati ṣojooro ninu eto idibo lai ni ọwọ ajọ eleto idibo ninu.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu yii, ni ẹgbẹ PDP tun fariwo mi-in ta ninu atẹjade kan ti alukoro wọn nipinlẹ Ondo, Kennedy Ikantu Peretei, fi ṣọwọ sawọn oniroyin pe aṣiri ọkan ninu awọn ọna ti ẹgbẹ APC fẹẹ fi ṣeru ninu eto idibo naa ti tu si awọn lọwọ.
Peretei ni, alaboojuto ajọ eleto idibo nipinlẹ Ondo ati awọn aṣaaju APC kan ti gbimọ pọ lati yi ifẹ ọkan awọn oludibo pada pẹlu bo ṣe jẹ pe orukọ eeyan meji meji lo ti fi silẹ lọdọ awọn ajọ to n ṣeto idibo naa gẹgẹ awọn ti yoo ba wọn ṣiṣẹ ni yuniiti kọọkan.
O ni awọn ayederu oṣiṣẹ wọnyi ni wọn fẹẹ lo lati le ṣe ojooro ti wọn ti pinnu ati ṣe, ki wọn baa le yege tipatipa ninu eto idibo naa.
Peretei ni, gbogbo nnkan ti awọn ṣakiyesi rẹ ree latẹyinwa, leyii to mu ki awọn maa ke tantan pe ko yẹ ko jẹ Abilekọ Babalọla ni wọn yoo mu wa gẹgẹ bii alaboojuto ajọ eleto idibo lati ṣeto naa, nitori awọn ko nigbagbọ ninu rẹ rara.
O waa fi asiko naa gba awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ati ajọ eleto idibo nimọran pe ki wọn tete yara tọwọ ọmọ iwakiwa ti wọn ba n gbero rẹ ninu eto idibo gomina to n bọ lọjọ Abamẹta yii bọ’ṣọ, nitori lọwọlọwọ ba a ṣe n sọrọ yii, oju gbogbo agbaye ti wa lara ipinlẹ Ondo, bẹẹ ni ko ṣẹni to le sapamọ sẹyin ika kan ṣoṣo.
Nigba to n fun Peretei lesi ọrọ rẹ, Alukoro ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Alex Kalẹjaye, ni airikanṣekan lo n yọ ẹgbẹ PDP lẹnu, nitori ẹgbẹ awọn ti ṣiṣẹ kọja ki awọn eeyan ma dibo fun awọn.
Kalẹjaye ni ko si idi kankan fawọn rara lati ṣeru, nitori gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo ni awọn ti polongo ibo de, awọn ti ba awọn eeyan sọrọ, ti wọn si ti ṣetan lati ṣe atilẹyin fun awọn lasiko eto idibo gomina ti yoo waye lọsẹ yii.
O ni ọpọlọpọ iṣẹ idagbasoke ni ẹgbẹ awọn ti ṣe, ti wọn si tun n ṣe lọwọ fawọn eeyan ipinlẹ Ondo, ti awọn yoo si tun tẹsiwaju lati maa parọwa fawọn araalu ki wọn le tẹsiwaju ninu atilẹyin wọn.