Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti parọwa si ẹgbẹ awọn olukọ fasiti lorileede yii, ASUU, atijọba apapọ lati fi pẹlẹ kutu yanju aawọ aarin wọn nitori ọjọ ọla awọn akẹkọọ.
Ninu atẹjade kan ti Ọba Akanbi fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibrahim, lo ti kọminu lori ọrọ eto ẹkọ lorileede Naijiria, o ni iyanṣẹlodi gbogbo igba ni ẹka naa jẹ akoba nla fun eto ọrọ-aje ati eto oṣelu lorileede yii.
O ke si awọn abala mejeeji lati jọ jokoo papọ, ki wọn damọran, ki wọn faaye gba awọn ori-ade lati ba wọn da si ọrọ naa, ki alaafia le jọba.
Oluwoo, ẹni to fa ara rẹ kalẹ lati wa lara awọn apẹtusaawọ laarin ASUU atijọba apapọ, sọ siwaju pe iyanṣẹlodi yii le da omi alaafia orileede Naijiria ru ti wọn ko ba tete gbe igbesẹ lori ẹ.
O ni ẹgbẹ ASUU ko nigbagbọ kankan ninu awọn oloṣelu mọ, idi niyẹn toun si ṣe n dabaa awọn ori-ade ti wọn yoo ri i pe ijọba ṣiika adehun ti wọn ba ṣe pẹlu awọn olukọ.
Ọba Akanbi fi kun ọrọ rẹ pe afara eto ẹkọ to ye kooro ti n wo lọ lorileede Naijiria, ko si si orileede to le ṣe daadaa lawujọ awọn orileede to ku ti eto ẹkọ wọn ko ba muna doko, idi niyi ti inu oun ko fi dun si iyanṣẹlodi gbogbo igba ni awọn fasiti kaakiri Naijiria.
O ke si ijọba apapọ lati mọ pe eto aabo yoo ṣoro diẹ ti wọn ko ba tete mojuto ọrọ iyanṣẹlodi yii, o si ke si awọn ASUU naa lati ro ti awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ọjọ ọla orileede yii mọ tiwọn.