Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ ti ju ThankGod Paule, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, si ẹwọn oṣu mẹfa lori ẹsun ole jija.
Paule, ẹni to n ṣiṣẹ lebiara ni wọn mu lọjọ karun-un, oṣu kejila, ọdun yii, lagbegbe Alaro, niluu Mọdakẹkẹ.
Agbefọba to mu Paule wa si kootu ṣalaye pe ṣe lo fọ ṣọọbu Ṣọla Adeyanju, to si ji awọn nnkan ti owo wọn din diẹ ni ẹgbẹrun marun-un naira.
Lara awọn nnkan ti olujẹjọ ji ni Irẹsi gbigbẹ, spagẹti, ọṣẹ ifọṣọ, indomi, siga rothmas ati benson ọti lile ti wọn n pe ni Agbara ati Halojin, bileedi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba ti wọn ka ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an si i leti, o ni oun jẹbi, ṣugbọn ki adajọ ṣiju aanu wo oun.
Ninu idajọ rẹ, Majisreeti O. B. Adediwura sọ pe ki Paule lọọ fi aṣọ pempe roko ọba fun oṣu mẹfa tabi ko ṣiṣẹ ilu (Community service) fun odidi oṣu kan.