Adewale Adeoye
Atẹnuje ti ko ba ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Sadiq Ahmed. Lẹyin to mu ọti burukutu tan, niṣe lo lọọ fipa ba ọmọbinrin kan ti ko ju ọmọ ọdun meje lo pọ, lawọn ọlọpaa ba gba a mu. Akolo awọn agbofinro agbegbe Abuja road, nijọba ibilẹ Yola South, nipinlẹ Adamawa, si lo wa bayii to ti n ṣalaye ohun to sun un dedii iwa ọdaran ọhun.
ALAROYE gbọ pe Sadiq fipa ba ọmọ naa sun lọjọ Aje, Monde, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lagbegbe Abuja Road, nijọba ibilẹ Yola South, nipinlẹ Adamawa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Suleiman Nguroje, to ṣafihan Sadiq lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, sọ pe baba ọmọ naa lo waa fọrọ ohun ti Sadiq ṣe fun ọmọ rẹ to awọn ọlọpaa leti, tawọn si lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ.
Alukoro ni, ‘Baba ọmọ ti Sadiq fipa ba sun lo waa fi ohun to ṣe fọmọ rẹ to wa leti. Baba naa sọ pe Sadiq wa sile oun lasiko toun ko si nile, to si fi Naira mẹwaa tan ọmọ naa lọọ ba sun.
‘A ti fọwọ ofin mu Sadiq, o ti si jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọ ọhun sun, o ni ọti burukutu kan toun mu yo lo fa a toun fi ṣiwa-hu pẹlu ọmọ naa’’.
Alukoro lawọn maa foju Sadiq bale-ẹjọ lẹyin tawọn ba ti pari iwadii awọn lori ẹsun tawọn fi kan an, ko le lọọ fimu kata ofin.