Atẹnujẹ ti ran Sheu lẹwọn o, ọgẹdẹ lo lọọ ji l’Akungba Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ Majisireeti kan to wa lagbegbe NEPA, l’Akurẹ, ti dajọ ẹwọn oṣu mẹta fun ọmọkunrin, Sheu Gambo, lori jijẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

ALAROYE gbọ pe ọdaran ọhun ni wọn lo ji paadi ọgẹdẹ mẹtala niluu Akungba Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun yii.

Ọgẹdẹ ọhun, eyi ti apapọ owo rẹ to bii ẹgbẹrun marundinlaaadọrin (#65,000) ni wọn lo jẹ ti Abilekọ Christianah Ushe.

Ẹsun ole jija ti i ṣe ẹsun kan ṣoṣo tí wọn fi kan Sheu ni wọn lo lodi, to si tun ni ijiya ninu labẹ ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Olujẹjọ ọhun ko wulẹ fakoko ile-ẹjọ ṣofo to fi gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa, o ni kile-ẹjọ jọwọ fiye denu, ki wọn si ṣiju aanu wo oun.

Agbejọro rẹ, Amofin Abdulsalam Musa, naa tun ba a bẹbẹ pe ki wọn ṣiju aanu wo o, niwọn igba ti ko ti fi asiko ile-ẹjọ ṣofo ati latari awọn ibi to fi ṣeṣe nitori lilu ti wọn ti kọkọ lu u nigba tọwọ tẹ ẹ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni ki ọdaran ọhun sare lọọ fẹwọn oṣu mẹta jura ninu ọgba ẹwọn Olokuta lai si owo itanran rara.

Adajọ ni oun mọ-ọn din ijiya rẹ ku lori bi ko ṣe gba akoko ile-ẹjọ ati ilukilu ti wọn ti kọkọ lu u tẹlẹ.

Leave a Reply