Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Wahala ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun tun gba ọna mi-in yọ pẹlu bi Igbakeji alaga wọn, Alagba Akanfẹ Atidade ṣe fẹsun kan Alaga, Ọnarebu Sọji Adagunodo, pe o ti gbowo ribiribi lọwọ Gomina Oyetọla lati doju ẹgbẹ naa bolẹ.
Atidade ni gbogbo aluwaala olongbo Adagunodo, ibi kikẹran jẹ lo mọ. O ṣalaye pe gbogbo bi Adagunodo ṣe lọọ gba ọfiisi tuntun laipẹ yii ko ṣẹyin ati da wahala silẹ ninu ẹgbẹ PDP.
Ṣugbọn Adagunodo ti sọ pe irọ to jinna soootọ ni Atidade n sọ. O ni ọkunrin naa lo bẹrẹ igbesẹ gbigba ọfiisi tuntun, bẹẹ lo ṣeto ikowojọ kaakiri lati fi sanwo rẹ nigba ti awọn idile Adeleke sọ pe awọn fẹẹ lo sẹkiteriati ti wọn wa tẹlẹ gẹgẹ bii ẹka yunifasiti wọn.
Gẹgẹ bi Atidade ṣe sọ ni tiẹ, ọwọ Gomina Oyetọla atijọba ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun ni Adagunodo ti gba owo to lọọ fi gba sẹkiteriati tuntun naa, bẹẹ lo si ti ṣeleri lati ba wọn ṣiṣẹ pọ lasiko idibo to n bọ.
O ni adehun to wa laarin Oyetọla ati Adagunodo ni pe dipo ko kuro ninu ẹgbẹ PDP, ṣe ni ko duro sibẹ lati maa ṣiṣẹ mọdaru, ko si maa gbe igbesẹ ti yoo da iyapa silẹ laarin ẹgbẹ.
“Irọ funfun balau ni Adagunodo n pa pe emi ni mo ba awọn kan sọrọ lati dawo ti wọn fi gba sẹkiteriati jọ. Aṣiri yii lo tu si awọn alakooso ẹgbẹ wa l’Abuja lọwọ ti wọn fi pe sẹkitetiati tuntun naa ni ọfiisi ajeji.
“Mo kan fẹ ki Adagunodo atawọn onigbọwọ rẹ ninu ẹgbẹ APC mọ pe ko si ọgbọn ti wọn le da, gbogbo awọn araalu ni wọn ti kọ wọn, o si di dandan ki agbara bọ lọwọ wọn lọdun 2020”