Atiku ati Okowa ṣepade pẹlu Jonathan l’Abuja

Monisọla Saka

Oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar ati igbakeji ẹ, Ifeanyi Okowa, ṣepade pẹlu aarẹ ilẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Ebele Jonathan, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, niluu Abuja. Okowa to tun jẹ Gomina ipinlẹ Delta lọwọlọwọ bayii lo gba ori ẹrọ alatagba Twitter ẹ lọ lati kede iroyin naa. Lasiko to gbe awọn fọto ti wọn ya nibi ipade ọhun sori ẹrọ ayelujara ni Okowa ṣalaye pe ọrọ lori bawọn ṣe maa gba ipo pada lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn wa lori aleefa bayii lọdun 2023 lohun tawọn jọ jiroro le lori.

O ni, “Awa niyi lalẹ ana (Tọsidee), aworan emi, oludije dupo aarẹ lẹgbẹ wa, Atiku Abubakar, nigba ta a jokoo ipade pẹlu aarẹ wa tẹlẹ, ọlọla julọ, Goodluck Jonathan. Nibẹ la ti fikun lukun lori erongba wa lati gba Naijiria pada loko ẹru”.

Bẹẹ naa ni Atiku funra ẹ ṣalaye lori ẹrọ ayelujara Facebook rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla yii, o ni, “Lalẹ ana, emi ati igbakeji mi lọọ ṣabẹwo alapọnle si aarẹ wa ana, Goodluck Jonathan, nile ẹ to wa l’Abuja.

Ninu fidio ti wọn gbe sori ayelujara ni aarẹ tẹlẹri ọhun ti ṣapejuwe Gomina Okowa gẹgẹ bii igbakeji aarẹ lọdun to n bọ. O fi erongba rẹ han pe oun ti ṣetan lati ti wọn lẹyin, koun si sa gbogbo ipa oun lati ri i daju pe ẹgbẹ PDP kẹsẹ jari ninu ibo ọdun to n bọ. Lẹyin eyi lo ṣadura fun wọn pe didun lọsan yoo so fun wọn. O ni paapaa ju lọ, gbogbo awọn ti wọn fẹẹ ṣoju wa lati ọdun 2023 lọ.

Jonathan tun fa Okowa lọwọ soke, pẹlu ẹrin musẹ lo si fi pariwo ẹ nigba to ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bii ‘igbakeji aarẹ wa tuntun to n bọ lọna’.

Leave a Reply