Atiku balẹ si kootu  ti wọn ti n gb’ẹjọ to pe ta ko Tinubu l’Abuja

Adewale Adeoye

Ṣe lẹsẹ ko gbero rara ni kootu kan ti wọn ti n gbọ ẹjọ to su yọ lori eto idibo to waye lorileede yii, ‘Presidential Elections Petition Tribunal’ (PEPT), to wa niluu Abuja, nigba ti Alhaji Atiku Abubarkar, to jẹ ondije dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP debẹ.

O ni oun paapaa fẹ waa foju oun ri bi igbẹjọ lori ẹjo toun pe naa ṣe fẹẹ lọọ.

Alhaji Atiku lo pe aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo nilẹ wa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati ajọ eleto idibo (INEC), lẹjọ pe ki i ṣe Tinubu lo wọle gẹgẹ bii alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Mammud Yakubu, ti ṣe kede rẹ pe oun lo wọle. O wa n rọ awọn adajọ ile-ẹjọ naa pe ki wọn wọgi le gbogbo eto idibo naa pata, ki wọn paṣẹ f’ajọ INEC pe ko ṣeto idibo tuntun mi-in ni kia bayii.

Ni nnkan bii ago mẹjọ aabọ aarọ kutu-kutu, Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un yii, ni Alhaji Atiku de sinu ọgba kootu naa pẹlu ogunlọgọ awọn ero lẹyin rẹ.

Lara awọn to tẹle e wa sile-ẹjọ ni awọn oloye inu ẹgbẹ PDP,  awọn ololufẹ rẹ gbogbo nilẹ yii ati loke okun atawọn alabaa-ṣiṣẹ-pọ rẹ.

Bẹẹ o ba gbagbe, Peter Obi to je ọmọ ẹgbẹ oṣelu ‘Labour Party’ (LP), paapaa wa nile-ẹjọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu yii, ati l’Ojoruu, Wesidee, ọjọ kẹwaa, oṣu yii kan naa, lakooko tigbẹẹjọ rẹ n lọ lọwọ.  

Pẹlu bawọn ọpọ ero ṣe tẹle Alhaji Atiku  wa si kootu, lo mu kawọn alaṣẹ ile-ẹjọ naa pese awọn ẹṣọ alaabo ti wọn pọ daadaa, lati le kapa ati pese aabo fun  Alhaji Atiku atawọn to wa nibẹ.

Nnkan bii ago meji ọsan ni wọn kọkọ sọ pe igbẹjọ Alhaji Atiku maa waye, ṣugbọn awọn alaṣẹ kootu naa deede yi i pada saaarọ Ọjọ’bọ, Tọsidee, ọjọ kọkànlá, oṣu yii bayii.  

Koko idi ti wọn ṣe gbe igbesẹ naa ko ye ẹnikẹni

Leave a Reply