Atiku dibo ni Adamawa, Rẹmi Tinubu di tiẹ n’Ikoyi

AWỌN ONIROYIN WA

Ajimuna ni oludije dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, fọrọ idibo naa ṣe pẹlu bo ṣe tete ji jade lọọ dibo ni wọọdu rẹ to wa ni Kwadabawa, Ajia 02, ni Iha Ariwa Yola, nipinlẹ Adamawa.

Nigba to sọrọ lori eto idibo naa lẹyin to dibo tan, ọkunrin ti wọn tun maa n pe ni Turaki Adamawa yii sọ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ ni mẹlọ mẹlọ yii, ireti wa pe ko ni i si idiwọ tabi wahala kankan fun awọn oludibo lati ṣe ojuṣe wọn. O ni gbogbo igbesẹ naa lo lọ nirọwọrọsẹ, ko si si wahala kankan rara toun fi dibo oun.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to dibo tan, Atiku ni oun nigbagbọ pe oun loun yoo gba ọpa aṣẹ lọwọ Aarẹ Buhari to n mura lati fi ipo naa silẹ bayii

Bakan naa ni iyawo oludije sipo aarẹ lẹgbẹ APC, Olurẹmi Tinubu ti dibo rẹ. Nigba to n sọrọ nipa bi eto idibo naa ṣe n lọ, obinrin to je senetọ nileegbimọ aṣofin agba yii ni ohun gbogbo lọ lai si wahala.

Leave a Reply