Atiku pe Tinubu nija: Yee sa kiri, jẹ ka jọ pade nibi apero ita gbangba 

Adewumi Adegoke

Oludije funpo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ti ke si oludije ẹgbẹ rẹ lati inu ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu pe ko yee sa kiri, to ba mọ pe oun laya, ko jade si gbangba, ko jẹ ki awọn pade nibi ipade ita gbangba, nibi ti awọn mejeeji yoo ti ba araalu sọrọ lori erongba wọn fun wọn.

Gẹgẹ bi iweeroyin Tribune ṣe sọ, Atiku Abubakar to gbẹnu agbẹnusọ rẹ lori eto ipolongo ibo, Kọla Ologbodiyan, sọrọ ṣalaye pe ki Tinubu yee sa kiri fun ipade ita gbangba. O ni ko jẹ ki awọn jọ koju ara awọn lati sọrọ nipa awọn eto ati erongba awọn fun araalu bii eto ọrọ aje, iṣejọba atawọn ohun gbogbo nipa igbesi aye awọn latẹyin wa.

Ologbodiyan ni, ‘‘A pe Tinubu nija ko jade sita ki oun ati Atiku Abubakar jọ ba araalu sọrọ lai kọ ohunkohun silẹ lori eto iṣejọba ati gbogbo ohun ti onikaluku wọn ni lọkan lati ṣe faraalu, nitori lati ọjọ yii ni Tinubu ti n sa fun ifọrowerọ pẹlu ẹnikẹni, bẹẹ lo si n sa fun awọn oniroyin pẹlu, ti ko feẹ ba wọn sọ ohunkohun.

‘‘Awọn aladaani nikan lo n ṣeto ipade pẹlu, eyi ti a si gbagbọ pe oun ni wọn n fi gbogbo ipade yii ṣegbe lẹyin. Akiyesi ta a si ṣe ni pe wọn yoo ti kọ ohun to maa sọ fun un ni iru awọn ipade bayii, tabi ko ma tiẹ sorọ rara, ko jẹ pe awọn kan ni yoo sọrọ tabi dahun ibeere to ba yẹ ko dahun.

‘‘O jẹ ohun ijọloju pe oludije funpo aarẹ ẹgbẹ APC yii n sa fun awọn ibeere, bẹẹ ni ko si fẹẹ sọrọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an nipa igbesi aye rẹ latẹyin wa.

‘‘Ṣugbọn ojuṣe rẹ ni lati ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ gẹgẹ bii ẹni to fẹẹ dari wọn. O gbọdọ pese ara rẹ silẹ lati dahun ibeere ọlọkan-o-jọkan ti wọn ba fẹẹ beere lọwọ rẹ, ko si jọwọ ara rẹ fun ifọrọwerọ ni ita gbangba. Atiku ti gbaradi lati fara han ni iru awọn ipade ita gbangba bayii, to si ti dahun ibeere lọlọkan-o-jọkan, nitori o ti gbaradi fun ipo aṣiwaju’’.

O waa fi kun un pe alubolẹ ni Atiku yoo lu Tinubu nibi ti eto idibo ti ko ni ojooro tabi magomago kankan ba ti waye.

Leave a Reply