Atiku tun gbọna ẹburu yọ si Tinubu lori ẹjo to pe

Adewale Adeoye

Ondije dupo ibo aarẹ to waye lorileede yii lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, lẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubarkar ti tun gbọna ẹburu mi-in yọ si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori bo ṣe sọ pe kileẹjọ faaye gba oun lati pe awọn ẹlẹrii mẹta ọtọọtọ kan ti wọn jẹ ojulowo oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa ( INEC), ti wọn ṣiṣẹ fun ajọ naa lakooko ibo gbogbogboo to waye gbẹyin nilẹ wa, koun le fidi rẹ mulẹ daadaa pe loootọ ni eru waye lasiko ibo to gbe Tinubu wọle.

ALAROYE gbọ pe gbara ti igbẹjọ ti Atiku pe bẹrẹ ni Ọjoruu, Wesidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni igbakeji aarẹ tẹlẹ naa ti rawọ ẹbẹ sawọn adajọ ile-ẹjọ to n gbọ ẹjọ eru to waye lakooko ibo aarẹ ilẹ wa, eyi to wa niluu Abuja, pe ki wọn faaye gba oun lati mu awọn ẹlẹrii mẹta kan jade ti yoo gbe ọrọ oun lẹsẹ pe eru wa ninu eto idibo to gbe Tinubu wọle.

Koko ohun ti Atiku n beere fun lọwọ awọn adajọ kootu ọhun ni pe ki wọn kede rẹ pe oun loun wọle sipo naa, tabi ki wọn wọgi le esi ibo to gbe Tinubu wọle, ki wọn si jẹ kawọn tun omiran di.

Alhaji Atiku ni eru to waye lasiko ibo naa lo jẹ ki Tinubu wọle, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ rara.

Ṣugbọn inu awọn lọọya alatako rẹ ko dun si igbesẹ ti ọkunrin oloṣelu ipinlẹ Adamawa yii fẹẹ gbe rara. Lara awọn agbẹjọro ti wọn ta ko aba Atiku ni lọọya Aarẹ Tinubu at ti igbakeji rẹ, Alhaji Shettima, lọọya ajọ INEC ati lọọya ẹgbẹ APC.

Ṣe lawọn agbẹjọro yii ṣokan, ti wọn si ta ko aba Alhaji Atiku yii. Ohun ti wọn n sọ ni pe ki awọn adajọ ile-ẹjọ naa ma ṣẹ faaye gba ẹbẹ ọkunrin naa rara.

Agbẹjọro to n ṣoju ajọ INEC, Abubarkar Mahoud, Akin Olujimi to n ṣoju Aarẹ Tinubu ati Lateef Fagbemi to n ṣoju ẹgbẹ APC ti gbogbo wọn pata jẹ agba agbẹjọro ( SAN) ni wọn fara ya gidi ni gbara ti wọn gbọ pe awon ẹlẹrii mẹtẹẹta ti Alhaji Atiku fẹẹ pe jẹ oṣiṣẹ ajọ INEC, ti wọn kopa pataki lakooko ibo aarẹ to waye nilẹ wa.

Nigba ti ọrọ ohun fẹẹ bẹyin yọ ni wọn ba sọ fawọn adajọ ile-ẹjọ naa pe ki wọn fun awọn laaye lati ṣara jọ lori ọrọ awọn ẹlẹrii ti Alhaji Atiku fẹẹ pe jade naa. Wọn ni igba akọkọ ree tawọn maa gbọ nipa awọn ẹlẹrii naa, to si yẹ ki awọn ti gbọ ṣaaju, ki awọn le mọ ohun tawọn maa bi awọn eeyan ọhun.

Ninu ọrọ tiẹ, Mahmoud ni ko sohun tuntun kan rara tawọn ẹlẹrii mẹtẹẹta ti Alhaji Atiku fẹẹ pe yii le sọ, ṣugbọn ki wọn sun igbẹjọ naa siwaju si i, koun le lanfaani lati wo inu iwe igbanisiṣẹ ajọ INEC, boya loootọ ni awọn ẹlẹrii naa jẹ ojulowo oṣiṣẹ wọn lasiko ibo aarẹ to waye gbẹyin gẹgẹ bi wọn ṣe sọ nile-ẹjọ naa.

Adajọ ti sun igbejọ naa si Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Leave a Reply