Monisọla Saka
Irọ pata ni pe ẹgbẹ wa ti fẹnu ko lati le awọn gomina ẹgbẹ PDP marun-un tinu n bi, eyi ti gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers jẹ adari fun wọn. Gomina ipinlẹ Delta, to tun jẹ igbakeji oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Ifeanyi Okowa, lo sọ eleyii di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, niluu Yenagoa, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Bayelsa, lẹyin ti wọn pari ipade awọn gomina apa Iha Guusu guusu ilẹ yii.
Okowa ni Atiku Abubakar to jẹ oludije dupo aarẹ ẹgbẹ awọn yoo ba awọn gomina maraarun naa jokoo ipade laipẹ yii lati fopin si aawọ aarin wọn.
O ni PDP ko ni i gba kawọn gomina marun-un ọhun binu fẹgbẹ silẹ, ati pe gbogbo ohun to n bi kaluku ninu ni yoo yanju laipẹ.
Okowa ni, “Irọ to jinna si ootọ ni ahesọ ọrọ ti wọn n gbe kiri pe awọn gomina marun-un ọhun fẹẹ fi ẹgbẹ silẹ. Ọkan naa ni gbogbo wa, mo mọ daju pe ikunsinu wa, wọn si ti n wa ojutuu si ọrọ naa. Laipẹ yii ni oludije dupo Aarẹ funra ẹ maa ba awọn gomina naa ṣepade. Gbogbo wa jọ wa ni, a si ti rira wa bi ẹbi kan naa, a o si le gba ki wọn ya kuro lara wa. Dajudaju, ọpọlọpọ iṣẹ lo ti n lọ labẹnu lati pari ija laarin tọtun tosi wọn ki nnkan si bẹrẹ si ni maa lọ deede pada.
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, Gomina Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue, Okezie Ikpeazu ipinlẹ Abia ati Gomina Ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi, lawọn maraarun ti wọn n binu lori bi alaga apapọ ẹgbẹ wọn, Iyorchia Ayu, ṣe kọ lati kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii adehun to ṣe ko too depo.
Lara awọn gomina ti wọn peju-pesẹ sibi ipade naa ni: Gomina Okowa, Udom Emmanuel ti ipinlẹ Akwa Ibom, Gomina Godwin Obaseki ti ipinlẹ Edo ati ojugba rẹ nipinlẹ Bayelsa, Sẹnetọ Douye Diri, to gba wọn lalejo.
Gomina ipinlẹ Rivers, to jẹ aṣaaju fawọn gomina tinu n bi naa ko mọ-ọn-mọ yọju sipade ọhun pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn gomina ti wọn wa lati apa Guusu Guusu tọrọ kan pata ni wọn wa nikalẹ.