Awọn nnkan kan wa ti mo ti kọja, n ko si ni i gba ẹnikẹni laaye lati fa mi pada sẹyin. Mo mọ pe Anti Sikira ki i ṣe eeyan daadaa, alaboosi kan bayii ni. Emi mọ ọn daadaa. Nitori ẹ ni ko ṣe le ri mi mu, afopina to loun fẹẹ pa fitila lọrọ ẹ, ara ẹ ni yoo pa ni. Mo sa sọ fun yin nijọ ti obinrin yii waa ka mi mọle, to bẹre si i bẹ mi o; to n sunkun si mi lọrun pe ki n dariji oun. Ọlọrun lo yọ mi ti n ko wi kinni kan fun un, ẹjọ oluwa–ẹ ni yoo maa gbe kiri bayii. Ṣugbọn mo ti mọ ọn daadaa. Mo mọ pe alareekereke eeyan kan ni, ko si le ri mi mu, eewọ ni.
Niṣe lo ma gbeja ko mi o, to ni alaidaa lemi, pe ara Iya Tọmiwa ọrẹ oun o ya, emi o si le sọ foun, emi wa n lọọ ki i lẹyin oun. Mo kan n fọwọ luwọ ni. Abi kin ni ki n ṣe! Ẹni to ba ẹfọn labata to yọ ọbẹ ti i, o ro pe omi lo mu ku ni. Ṣe bi oun ba ri Iya Tọmiwa nigba ti ko le rin, ti ko le da ṣu, ti ko le da tọ, ṣe oun le mu un lọrẹẹ. Ṣebi nigba to de to ri Iya Tọmiwa ti ara ẹ da pe, to n redi loju agbo ijo, iyẹn lo ṣe ro pe oun ti ri ọrẹ pataki. Ka tiẹ waa pa iyẹn ti. Bi o ba je ọrẹ eeyan, ti ara tọhun o ya, to ba fẹ ko o roun tabi ko o waa wo oun, ṣe ko ni i pe ẹ tabi ko ranṣẹ si ẹ!
Ẹni to o pe ni ọrẹ ẹ ko ranṣẹ si ẹ, emi lo wa n tori iyẹn ba ja. Ṣugbọn ọtọ lohun to n ṣe e. Ọrọ Safu lo fẹẹ maa tori ẹ daamu ara ẹ, lai ṣe emi. Safu o si raaye tiẹ, o ti ni bo ba ṣe gbe e wa loun yoo gbe e fun un. Ọmo to jẹ iṣẹ okoowo ẹ lo gbaju mọ, nigba to si ge awọn aṣọ tuntun kan sara laipẹ yii ninu owo to gba, ko si ara Agege ti wọn jọ wa tẹlẹ ti yoo fẹẹ da a mọ mọ. Awọn aṣọ gidi lo n ra sara. Ki i ṣe faari aṣeju o, ṣugbọn ko sẹni to maa ri awọn aṣọ ẹ ti ko ni i mọ pe wọn ki i ṣe bọsikọna, aṣọ gidi ni wọn. Iyẹn n mu inu emi dun lọtọ, nitori o gbọ faari ju gbogbo wa lọ.
Bẹẹ ni ki i ṣe pe mo n fun un lowo kan to ju iṣẹ to n ṣe lọ, koda n ko fun un lowo to yẹ ki n maa fun un, nitori emi naa tun n jere lara ẹ ni. Ko si ọjọ kan to de ṣọọbu ti ko ni i ri ọja ta. Yoo pa owo ṣaa ni, owo gidi ni yoo si pa. Emi o si ni i jegun mọyan ni temi, owo to ba tọ si i, n oo fun un ba a ba ti n dele ni. Kia lo ti gbajọba mọ awọn ọmọ ṣọọbu lọwọ. Ati Abbey ni o, ati Raṣida ni o, ko sẹni to le woju ẹ ninu gbogbo wọn. Oun naa kuku tiẹ maa n fun wọn ni nnkan: o le ra miniraasi fun wọn, tabi lọjo mi-in ko ni ki wọn lọọ ra iyan wa ki gbogbo wọn jẹ. Awọn yẹn naa fẹran ẹ, wọn ti ri i bi ọga ati aunti wọn.
Ile nikan ni wahala wa, nitori Sẹki gan-an ti waa woran ẹ, o si ti mu un lọrẹẹ debii pe wọn ti jọ n raṣọ kan naa. Sẹki gan-an maa n fẹ ko tẹle oun lọ sibi ti oun ba ti fẹẹ raja, tabi lọjọ ti awọn kan ba fẹẹ gbe iṣẹ kan fun un. Ṣugbọn awọn araale ko fi oju daadaa wo o. Iya Dele n binu, ṣugbọn ko fi tiẹ han. Aunti Sikira lo ni wahala ibẹ ju. Nitori pe ọmọ yẹn n wọṣọ daadaa, o si n rowo tunra ṣe: nigba to n ṣiṣẹ. Alaaji ko le fi i silẹ, niṣe lo n gbọn le e lẹyin, gbogbo ohun to n ṣe fun Aunti yẹn tẹlẹ, Safu lo ku to n ṣe e fun. Ohun to faja gan-an niyẹn.
Aunti Sikira kọkọ sọ fun ọmọ yẹn pe gbogbo nnkan to ba fẹẹ ṣe ninu ile yẹn, o gbọdo maa gbaṣẹ lọwọ oun, nitori oun ni iyaale ẹ. Ọmọ si ni oun ti gbọ. Ko kuku si ohun to pa wọn pọ, o ni awọn ko le gbun ara awọn nitori oun ko ni ohun ti oun fẹẹ lọọ gba lọwọ ẹ. Aunti yẹn gan-an mọ pe ihalẹ irọ loun n ṣe, abi ki lo fẹẹ ni ko too ṣe ko waa sọ foun. Iṣaasun ko pa wọn pọ, iṣẹ ko so wọn pọ, owo ko da wọn lu, ki lo waa fẹẹ maa ni ko waa sọ foun. Afi lọjọ to bẹrẹ si i ba mi ja nitori ọrọ Iya Tọmiwa yẹn, ọjọ yẹn ni Safu jẹwọ ọmọ Agege fun un.
Emi o kuku tiẹ wobẹ, gbogbo ohun to n sọ, mo kan mọ ọn loju, mo yipada, mo n gun oke lọ ni, nitori ọdọ iya mi ni mo ti n bọ ni yara wọn to fi ri mi to bẹrẹ si i ja bọ bẹẹ. Aṣe bi emi ṣe gun oke ni Safu jade, o ba a nibi to ṣi n rojọ, bo si ti ri i lo ni ko lọọ ṣọra ẹ gidi, iya ẹ tuntun to n tẹle yẹn lo maa ko ba a ninu ile Alaaji, nitori oun jọ maa fi wa wọlẹ papọ ni. Nibẹ ni Safu ti da a lohun. Iyẹn sọ fun un pe bi oun ṣe wa yii, o le bu oun daadaa, koda o le fọ oun leti ti oun ko ni i gbin, ṣugbọn to ba kọ lu iya oun loju oun, oun maa ba a fa a o.
Niṣe l’Aunti Sikira pariwo, ariwo yẹn lemi gbọ ti mo fi tun n pada sọkalẹ. O ni ti Safu ba tun sọ bẹẹ, oun maa fọ o leti gidi. Ni Safu ba ni ko ma dan an wo: to ba dan an wo, o maa dan an tan ni o. Anti Sikira ko jẹ kọmọ yẹn sọ bẹẹ tan to fi fọ ọ leti, lau! Emi o ti i desalẹ, mo ṣi n bọ ni, ṣe ka ni mo ti debẹ, n ba le dabọ biliisi to fẹẹ ṣẹlẹ. Safu ko jẹ ki eti ti Anti Sikira fọ oun tutu, kia lo fi ọwọ mejeeji da a pada fun un, o fi ọwọ ọtun gba eti ọtun, o fi osi gba eti osi, l’Anti Siikra ba lọgun too, mo gbọ, ‘O pa mi ooo!’ Ọlọrun, mo ṣẹṣẹ gba pe Aunti yii o lojuti ni.
Abi keeyan maa lọgun bẹẹ yẹn fun ọmọde abẹ ẹ, ki Aunti Sikira maa lọgun pe Safu pa oun. Ariwo to ṣaa pa lo gbe Alaaji sare jade, atemi naa. Nigba ta a fi maa de ṣa, Safu ti palẹ Aunti Sikira mọ, afi gbimu lo sọdi ẹ mọlẹ, niyẹn ro bii apo elubọ! Gbogbo bi Aunti Sikira ṣe n ja watiwati to, ọmọ yẹn n ko ifọti fun un lọ ni. Koda, ọkọ wọn mu un ti, Alaaji to jẹ o n maa n sa funja ni, nigba to ti ri i pe kinni naa ti le to bẹẹ, ariwo ‘Sikira! Sikira!’ lo n pa. Emi ni mo ṣẹṣẹ jagbe mọ ọn, ti mo ni, ‘Safuuu!’ Lo ba fi Aunti Sikira silẹ, lo sa wọle lọ.
Bo ṣe n sare wọle lọ ni Anti Sikria tun ta ragbaragba dide, o fẹẹ maa le e lọ, afi wọọ lo ba tun digbo lulẹ. Ọkọ ẹ lo n fa a dide, ṣugbọn ija lo n ba a ja. ‘Ṣo o ri nnkan tiyawo ẹ ṣe fun mi! Ṣe o ri nnkan ti ọmọ-oṣi to o gbe wale ṣe fun mi!’ Nigba yẹn lemi ti yaa pada soke, kẹnikan ma fọrọ ti ki i ṣe temi ra mi lara. Bi ki i baa ṣe pe agbalagba kọja aye ẹ, ṣe obinrin to n tile ọkọ kan bọ, to ti bimọ rẹpẹtẹ sọhun-un, to jẹ aya lo fi n gbe apo irẹsi loun nikan ni ṣọọbu, ṣe iru obinrin bẹẹ leeyan n kọkọ yara fọ leti. Ọrọ naa dun mi, ṣugbon alaṣeju l’Aunti Sikira naa; ki i gbọran, o kan ko ara ẹ siya jẹ ni!