Ọlawale Ajao, Ibadan
Fun ẹsun iwa ọdaran to ni i ṣe pẹlu biba nnkan jẹ, Alakooso awọn awakọ ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Mukaila Lamidi, ẹni ti gbogbo aye mọ si Auxilliary ti n kawọ pọyin rojọ ni kootu bayii.
Nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla yii, lawọn ọlọpaa mu oga awọn onimọto naa.
Nile Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, la gbọ pe wọn ti mu un nirọlẹ ọjọ naa ki wọn too pada gba beeli rẹ.
Ṣugbọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọwale Williams, pada gbe e lọ si kootu lati jẹjọ awọn ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an niwaju adajọ.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ lọga agba awọn ọlọpaa fi kan Auxilliary. Akọkọ, wọn ni lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 ta a wa yii, oun pẹlu awọn afurasi ọdaran kan jọ gbimọ-pọ lati ba dukia onidukia jẹ laduugbo kan ti wọn n pe ni Igboọra, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ariwa Ibadan.
Ninu ẹsun keji, wọn ni “Ni nnkan bii aago meje alẹ ku iṣẹju mẹwaa lọjọ naa, lagbegbe ta a darukọ siwaju yii, iwọ Mukaila Lamidi, ẹni ọdun mọkanlelọgọta (61), pẹlu awọn kan ti wọn ti sa lọ bayii, jọ lẹdi apo pọ, ẹ si ba patako ipolongo ibo oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu jẹ”.
Bamubamu lawọn tọọgi kun agbegbe kootu Majisreeti to wa ninu ọgba ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibadan naa, iṣẹ nla si lawọn agbofinro ṣe lati ri i pe awọn eeyan naa ko wọ inu kootu lati fa wahala titi ti igbẹjọ to n lọ lọwọ lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ yoo fi pari.