Adewale Adeoye
Fun igba akọkọ lati igba ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti kede pe ijọba oun ko ni i le sanwo iranwọ lori epo bẹntiroolu, apapọ awọn gomina ẹgbẹ APC ti sọ pe awọn fara mọ igbesẹ ti Aarẹ gbe lori ọrọ naa, tawọn yoo si ṣatilẹyin gidi fun un ko le ṣaṣeyọri ninu igbesẹ ọhun. Wọn ni eyi jẹ ọkan lara awọn ileri ti Tinubu ṣe lakooko to n ṣepolongo sipo aarẹ orileede yii, ti wọn si tun sọ pe oun paapaa ti n ṣeto gidi kan lati bu ororo itura si inira yoowu ti igbesẹ ọhun le fẹẹ mu ba awọn araalu bayii.
Alaga awọn gomina ẹgbẹ APC to tun jẹ gomina ipinlẹ Imo, Sẹnetọ Hope Uzodima, lo sọrọ yii di mimọ nibi ipade pataki kan to waye laarin awọn gomina ọhun ati alaga ẹgbẹ wọn, Senetọ Abdullahi Adamu, niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.
Gomina Hope ni ko si ninu awọn alatako ti wọn dije pẹlu Aarẹ Tinubu ti wọn ko sọ pe awọn paapaa maa fopin sowo iranwọ lori epo naa nitori wọn mọ daadaa pe ko sowo lapo ijọba apapo ilẹ yii mọ lati maa san fawọn oniṣowo ti wọn n gbe epo naa wa silẹ wa mọ.
O ni, ‘Gẹgẹ bii ẹgbẹ to nitumọ, a gbọdọ ṣohun gbogbo lati ṣatilẹyin gidi gun Aarẹ Tinubu ti i ṣe ọmọ ẹgbẹ wa, ko sohun to ṣe ta a maa ta ko rara, ajọmọ ẹgbẹ lohun ti Tinubu n ṣe bayii, eyi si wa lara awọn ohun to ti sọ pe oun yoo ṣe faraalu nigba to n ṣepolongo ibo rẹ lọwọ. Bẹẹ ba si wo o daadaa, gbogbo awọn to dije dupo aare pẹlu Tinubu ni wọn sọ pe awọn naa maa yọ owo iranwọ kuro lori epo yii, wọn mọ daadaa pe ko sowo kankan mọ lapo ijọba orileede yii lati maa fi sanwo naa lọ fawọn onsiwo gbogbo ti wọn n gbe epo wa fun wa. Ijọba si ti n ṣe awọn ohun kọọkan labẹnu bayii lati le din inira yoowu ti igbesẹ naa le fẹẹ mu wa fawọn araalu. A ni igbagbo ninu iṣakooso Aarẹ Tinubu pe yoo gbe orileede yii de ebute ayọ, tawọn ọmọ orileede yii yoo si maa dunu pe awọn ti ri olori to daa lopin ohun gbogbo