Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lati le wa ojutuu si wahala aisi eto aabo to peye lorileede Naijiria, Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, ti ke sijọba apapọ lati gbe iṣakoso eto aabo le awọn ori-ade lọwọ.
Ọba Akanbi, ẹni to ṣapejuwe awọn ọba alaye gẹgẹ bii ẹni to mojuleja eto aabo, nitori naa ni wọn ṣe nilo agbara ofin ati owo to pọ lati fi ṣiṣẹ naa.
O ṣalaye pe iṣoro aisi eto aabo lorileede yii lọwọlọwọ kuro ni nnkan ti awọn kan a kan maa sọrọ le lori lojoojumọ lai gbe igbesẹ to tọ, ṣe lo si yẹ kijọba apapọ ṣa awọn ọba ti wọn kunju oṣunwọn lati ṣiṣẹ naa takuntakun pẹlu owo.
Oluwoo fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ alaabo ni wọn maa n wo oju awọn ori-ade to ba ti di ọrọ eto aabo, idi niyi tijọba fi nilo lati fi owo ti igbesẹ naa nilo fun awọn lọbalọba.
Gẹgẹ bi Ọba Akanbi ṣe wi, “Ọna kan ṣoṣo lati dẹkun wahala aisi eto aabo ni lati fun awọn ori-ade ni agbara ofin ati owo. Gẹgẹ bii baba fun gbogbo ilu, mo mọ gbogbo kọrọkọndu agbegbe yii.
“Mo ni awọn baalẹ, awọn oloye ati awọn ọmọ ọba kaakiri agbegbe mi. Ti ohunkohun ba ṣẹlẹ nibikibi, mo mọ ẹni ti mo maa pe fun alaye kikun. Ti wahala kankan ba ṣẹlẹ, awọn ti mo yan gbọdọ le mọ ẹni ti a maa mu. Ko sẹni to le ṣe mọnamọna nibi.
“Mo n rọ ijọba apapọ lati tubọ gbe agbara wọ ẹka awa lọbalọba. Ibi ti ọrọ orileede yii de bayii nilo ka ti ọwọ awa ọba bọ ọ. Ọba to ba mọ nnkan to n ṣe gbọdọ mu ọrọ eto aabo lọkunkundun.