Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ẹka ti wọn ti n gbọ ẹsun ipaniyan ni ọkunrin kan bayii torukọ ẹ n jẹ Wasiu Adegbenro, wa bayii, nipinlẹ Ogun. Idi ni pe o gba ọkunrin kan to n wa kẹkẹ Maruwa lẹṣẹẹ lọsan-an ọjọ Ẹti to kọja yii, ni marosẹ Eko s’Ibadan, n lọkunrin naa torukọ ẹ n jẹ Oseni Sẹmutu ba bẹrẹ si i pọ ẹjẹ, bo ṣe ku niyẹn.
Ohun ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, sọ lori iṣẹlẹ yii ni pe ọrọ kan lo di ija laarin Wasiu to n wa tirela ati Oseni to n wa Maruwa, lo ba di pe wọn yọwọ ẹṣẹ sira wọn, iyẹn ni nnkan bii aago meji ọsan kọja ogun iṣẹju lọjọ Jimọ naa.
Nibi ti wọn ti n ja ija ọhun ni Wasiu ti fun Oseni lẹṣẹe kan to lagbara, bi Oseni ṣe bẹrẹ si i pọ ẹjẹ lẹnu niyẹn ti ẹjẹ si tun n yọ nimu rẹ pẹlu.
Ọrọ di ti ọlọpaa gẹgẹ bi Alukoro ṣe wi, awọn ọlọpaa naa ni wọn si sare gbe Oseni lọ si ọsibitu to wa nitosi, ṣugbọn awọn dokita sọ pe ẹṣẹ to jẹ ko maa pọ ẹjẹ naa ti pa a, bi ọkunrin oni Maruwa naa ṣaa ṣe jẹ Ọlọrun nipe niyẹn.
Ẹsẹkẹsẹ ni wọn ti mu Wasiu ti wọn lo fi ẹṣẹ pa a ju satimọle, CP Edward Ajogun si ti paṣẹ pe ki wọn mu un lọ sẹka to n gbọ ẹsun awọn apaniyan, ibẹ lo wa ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.