Awakọ to ba fa wahala nipinlẹ Ọyọ yoo jẹ baba nla iya- Ọmọlẹwa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Alaga igbimọ to n dari awọn awakọ ero nipinlẹ Ọyọ, Alaaji Tọmiwa Ọmọlẹwa, ti kilọ fawọn oloye igbimọ naa kaakiri ipinlẹ ọhun lati yago fun iwa to le da omi alaafia ilu ru.

Ikilọ yii waye lasiko ti Ọmọlẹwa ṣepade pẹlu awọn olori igbimọ naa ti wọn n pe ni PMS bayii, nijọba ibilẹ Ẹgbẹda, nipinlẹ Ọyọ.

Ninu ipade ọhun ni Tommy, gẹgẹ bii inagijẹ ti wọn n pe e, ti gba alaga igbimọ naa l’Ẹgbẹda nigba kan ri, Alhaji Suraju Adio, sinu igbimọ to n dari awọn awakọ ero pada.

Nigba to n lu aago ikilọ naa si wọn leti, o tẹnu mọ ọn pe ko si aaye fun jagidijagan ninu ẹgbẹ awakọ mọ, ọga awọn awakọ ero yii sọ pe ẹnikẹni to ba fa wahala, tabi faaye gba wahala lagbegbe to n mojuto, baba nla iya loluwarẹ yoo jẹ nitori ko sẹni to ga kọja ofin.

Tommy waa rọ awọn oṣiṣẹ ajọ naa kaakiri ipinlẹ Ọyọ lati mojuto awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kaakiri ipinlẹ yii, nitori olori ni yoo jiya ẹṣẹ yoowu ti awọn ero ẹyin wọn ba ṣẹ.

Bakan naa lo kilọ fun gbogbo ọmọ igbimọ ọhun, ati gbogbo awakọ paapaa lati yago fun iwa ti ko ba afojusun Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti i ṣe gomina ipinlẹ naa mu.

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni Gomina Makinde yan Tommy atawọn ẹmẹwa ẹ gẹgẹ bii igbimọ alakooso ẹgbẹ awọn awakọ ero lẹyin to fọwọ osi juwe ile fun awọn Alhaji Mukaila Lamidi, ti gbogbo aye tun mọ si Auxiliary, to n dari igbimọ ọhun ṣaaju asiko naa.

Latigba naa lalaafia ti n jọba laarin awọn onimọto n’Ibadan ati kaaakiri ipinlẹ Ọyọ.

 

Leave a Reply