Adebiyi Adefunkẹ, Abẹokuta
Ẹwọn ọdun mẹrin aatabọ lai ni owo itanran ninu rara ni kootu Majisreeti Ọta paṣẹ pe ki ọkunrin ẹni ogun ọdun kan, Awalu Usman, lọọ ṣe bayii nitori ọkunrin ẹgbẹ rẹ, Adeyẹmi Adeniji, to gun lọbẹ lagbegbe Ijaba, Ọta, nipinlẹ Ogun, lọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020.
Adajọ S.S Shotayọ lo gbe idajọ naa kalẹ lọsẹ to kọja yii, lẹyin ti Agbefọba, Cynthia Ejezie, ti ṣalaye pe ija ṣẹlẹ laarin olujẹjọ atawọn kan ti wọn ti sa lọ bayii, nigba naa ni wọn yọ ọbẹ, ti wọn si fi gun Adeyẹmi, ti wọn ṣe e leṣe kọja sisọ, to bẹẹ to jẹ Ọlọrun lo yọ ọkunrin naa ti ko fi ba iṣẹlẹ naa lọ.
Eyi lo fa a to fi jẹ ẹsun igbiyanju lati paayan ni wọn fi kan Awalu, oniṣowo nitosi ibi to ti gun Adeyẹmi lọbẹ.
Oun funra ẹ naa jẹwọ pe loootọ loun gun olupẹjọ lọbẹ, o ni inu lo bi oun toun fi fa ọbẹ yọ pẹlu awọn eeyan oun yooku, tawọn si fi gun Adeyẹmi kaakiri ara rẹ.
Awalu loun jẹbi ẹsun igbiyanju lati paayan ti ile-ẹjọ fi kan oun naa.
Adajọ Shotayọ sọ pe ko si atotonu kankan mọ lori ẹjọ yii, o paṣẹ pe ki Awalu lọọ lo oṣu mẹrinlelaaadọta (54 months) lẹwọn, eyi ti i ṣe ọdun mẹrin aabọ, gẹgẹ bii ijiya fun ẹṣẹ to ṣẹ ninu oṣu kẹsan-an, ọdun yii.