Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọwọ awọn agbofinro tun ti tẹ awọn Fulani mi-in ti wọn ji ọkunrin agbẹ kan, Fatai Ogunniyi Adeagbo, gbe niluu Igboọra. Ileewosan la gbọ pe Fatai Adeagbo, ẹni to ni ipenija aisan ibà n lọ lati lọọ gbatọju ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee to lọ lọhun-un, ti awọn gende ọkunrin marun-un fi da oun pẹlu iyawo ẹ, Abilekọ Bọlaji Adeagbo ti wọn jọ n lọ lọna pẹlu ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in lọwọ, ti wọn si ji ọkunrin agbẹ naa gbe.
Ere àsáṣubú-lọ́nà lAbilekọ Bọlaji sa dele pẹlu omije loju. Lẹsẹkẹsẹ lawọn agbaagba adugbo lọọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti.
Lọjọ keji lawọn ajinigbe ọhun pe awọn mọlẹbi ọkunrin naa lori ẹrọ ibanisọrọ pe ki wọn san miliọnu mẹwaa Naira (N10m) fawọn ki wọn too le ri ẹni wọn to wa lakata awọn gba pada laaye.
Lẹyin ti awọn ẹbi Fatai ti gbe owo lọọ pade wọn ni wọn too yọnda baba agbẹ naa bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe iye ti awọn olubi eeyan yi beere ni wọn ri fun wọn. A ko si mọ pato iye owo ọhun titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.
Sugbọn ọlọpaa ko sinmi wiwa awọn afurasi ọdaran yii, awọn mẹfẹẹfa lọwọ wọn si pada tẹ lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ti ṣiṣẹ laabi naa. Fulani ni gbogbo wọn.
Ọmọdọde gbaa lawọn afurasi ọdaran yii, eyi to dagba ju ninu wọn lo jẹ ọmọọdun mẹtalelogun (23). Meji ninu wọn, iyẹn Umaru Lawal ati Adamu Bahago ko ju ọmọ ogun (20) ọdun pere lọ.
Orukọ awọn yooku pẹlu ọjọ ori wọn ni Wetti Abubakar, ọmọọdun mọkanlelogun (21); pẹlu Yahya Mohammed ati Manu Tambaya ti wọn jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun (23) ni tiwọn.
Ta o ba gbagbe, laipẹ yii lawọn Fulani mẹrin kan naa lọọ da agbẹ kan pẹlu afẹsọna rẹ lọna ti wọn si ji eyi obinrin gbe lẹyin ti wọn yinbọn pa ololufẹ ẹ niṣeju ẹ niluu Igboọra yii kan naa.