Ọlawale Ajao, Ibadan
Bi gbogbo Musulumi kaakiri agbaye ṣe n dunnu, ti wọn yọ, lasiko ọdun Ileya tọdun 2020 yii to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ọrọ ko ri bẹẹ fawọn Fulani mẹta kan, Buba Bello, Buba Shatari ati Aliu Beidu, pẹlu bi wọn ṣe ṣọdun naa ninu ahamọ awọn agbofinro. Maaluu nla nla meji to jẹ ti Fulani ẹgbẹ wọn ni wọn ji gbe.
Meji ninu awọn afurasi ole mẹta yii, Buba Bello ati Buba Shatari, ni wọn jẹ ọmọ iya kan naa. Bello to jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) lẹgbọn, nigba ti Shatari to jẹ aburo ko ju ẹni ogun (20) ọdun lọ. Ọmọ ipinlẹ Kwara lawọn mejeeji.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Aliu Beidu, ẹni ogun ọdun, to jẹ ọmọ ipinlẹ Niger, ṣugbọn to fi Aba Bọlọrunduro, lóríko ilu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, ṣebugbe, lo ranṣẹ pe Bello ati Shatari pe ki wọn ti ipinlẹ Kwara ti wọn n gbe waa dara pọ mọ oun lati ji maaluu Fulani ẹgbẹ wọn to n jẹ Mohammed Bello gbe.
Nibi ti wọn ti fẹẹ ta maaluu ọhun ninu ọja Kaara to wa niluu Ogbomọṣọ, lawọn oṣiṣẹ sifu difẹnsi ti lọọ mu wọn lẹyin ti baba onimaaluu ti ri awọn maaluu ọhun, to si ti ta awọn agbofinro naa lolobo.
Ko si eyi to gbọ ede Oyinbo tabi Yoruba ninu awọn afurasi ole mẹtẹẹta wọnyi, ṣugbọn pẹlu bo ṣe jẹ pe nigba tọdun Ileya ku ọsẹ kan ni wọn jale naa, igbagbọ ọpọ eeyan ni pe niṣe ni wọn fẹẹ fowo maaluu onimaalu naa ṣọdun, lai mọ pe inu atimọle tabi ọgba ẹwọn nigbesẹ naa yoo ja si fawọn nigbẹyin.
Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ole yii fawọn oniroyin n’Ibadan, ọga agba ajọ ẹṣọ alaabo ilu ta a mọ si sifu difẹnsi nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Iskilu Akinsanya, sọ pe apapọ owo maaluu mejeeji ti wọn ji gbe to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000).
O ni lọsẹ yii loun yoo foju awọn mẹtẹẹta bale-ẹjọ ni kete ti iwadii awọn ba pari lori iṣẹlẹ naa.