Ọlawale Ajao, Ibadan
Mẹrin ninu awọn to lugbadi ajakalẹ arun Korona ti sa kuro nibi ti wọn ti n gba itọju niluu Igbẹti, nipinlẹ Ọyọ laipẹ yii.
Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, eeyan mẹjọ larun Korona ti ran lọ sọrun ọsan gangan nipinlẹ Ọyọ, apapọ awọn to ti lugbadi arun naa nibẹ ti to nnkan bii ojilenirinwo (440) eeyan, mẹrindinlọgọsan-an (176) ninu wọn lo si ti gbadun lẹyin ti wọn ti gbatọju nileewosan ijọba.
Nibi eto itaniji ati idanilẹkọọ ti ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ọyọ ṣe fawọn oniroyin n’Ibadan lọsẹ to kọja ni wọn ti fidi awọn iroyin yii mulẹ.
Nigba to n sọ nipa ọṣẹ́ ti ajakalẹ arun Korona ti ṣe kaakiri agbaye, Olootu agbekalẹ eto gbogbo nileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ọyọ, Dokita Korede Ekume, fidi ẹ mulẹ pe eeyan bii miliọnu mejọ laṣekupani arun naa ti mu kaakiri agbaye bayii.
O ni yatọ si titẹle awọn ilana ti awọn eleto ilera la kalẹ, ọna to dara ju lati di ara ẹ lámùrè laarin awọn eeyan lawujọ ni ki tọhun ri gbogbo eeyan gẹgẹ bii ẹni to ti ni arun naa lara, eyi ni yoo jẹ ki iru ẹni bẹẹ le ṣọra lati maa sun mọ ẹnikẹni lawujọ, ti ẹnikẹni ko si ni i le ko arun naa ran an.
Igbakeji olùtanijí agba lori eto ilera nipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Ọladele Fọlaṣade, ẹni to kin ọrọ yii lẹyin, fi kun un pe eeyan mẹrin lo sa lọ nibi ti wọn ti n gbatọju arun Korona niluu Igbẹti. Idi niyẹn to fi yẹ ki gbogbo eeyan maa ṣọra lati maa fara kan awọn eeyan tabi sun mọ ẹnikẹni ju bo ṣe yẹ lọ.
Gẹgẹ bi aṣoju World Health Organisation (WHO), iyẹn ajọ to n ṣakoso eto ilera lagbaaye, Dokita Marcus Oluwadare, ṣe sọ ninu ọrọ tiẹ, o ni o ṣe ni laaanu pe bi ajakalẹ arun Korona ṣe n gbilẹ si i lawọn eeyan tubọ n foju di i, ti wọn si n tapa si awọn ilana ti ajọ WHO la kalẹ lati maa fi dena arun yii.
“Ọpọ eeyan n rin kaakiri ilu lai lo ibomu, awọn ọlọkada ṣi n gbero meji, ti awọn onimọto naa si n kérò kún inu mọto wọn bamubamu. Iru awọn iṣesi wọnyi ko jọ iṣesi to yẹ ko maa waye niru asiko bayii to jẹ pe ajakalẹ arun n da gbogbo aye laamu.”