Awọn ṣọja ṣawari ileeṣẹ ti wọn ti n ta ọmọ tuntun, ọpọlọpọ aboyun ni wọn ko kuro nibẹ

Monisọla Saka

Ọwọ palaba awọn amookunṣika ẹda ti ṣegi pẹlu bi awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria, ẹka ti 14 Brigade, Ohafia, nipinlẹ Abia, ti tẹ wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Ileeṣẹ tawọn ẹni ibi yii ti n ta awọn ọmọ tuntun bii ẹni ta burẹdi ni wọn da silẹ, ti wọn si tun forukọ ẹ silẹ lọdọ ijọba gẹgẹ bii ile awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn n ran awọn eeyan lọwọ, ti wọn si n ṣetọju awọn ọmọ alaniyaa, eyi ti wọn pe ni Nma Charity Home.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lawọn ṣọja ya wọ ileeṣẹ to wa lagbegbe Umunkpei Nvosi, nijọba ibilẹ Isiala-Ngwa, nipinlẹ Abia yii, lati wo nnkan to n ṣẹlẹ nibẹ, lẹyin tawọn kan ta wọn lolobo pe

awọn olubi ẹda ti wọn n fọmọ ṣetutu tabi oogun owo lobinrin naa maa n ta awọn ọmọ yii fun. Bẹẹ lawọn ti wọn n ṣe aratunta ọmọ, to fi mọ awọn ti wọn n ko wọn lọ silẹ okeere lọọ fi ṣowo ẹru naa maa n ra ọmọ lọwọ wọn.

Wọn ni nibi ti aaye gba obinrin naa de, awọn eeyan maa n ri ẹya ara eeyan layiika ile ọhun. Ati pe, lọpọ igba lawọn agbefọba nipinlẹ naa ati ipinlẹ mi-in ti waa yẹ ile naa wo latari awọn iwa to mu ifura lọwọ ti wọn n gbọ nipa ẹ. Ṣugbọn obinrin to nileeṣẹ naa maa n sa lọ ni bi wọn ba ti wa sibẹ, tawọn agbofinro yoo si doola awọn ọmọbinrin ti wọn n lo lati fi ṣiṣẹ buruku naa.

Awọn ọdọmọbinrin bii mọkanlelogun, tọjọ ori wọn ko ti i to ogun ọdun, ti wọn wa ninu oyun ni wọn ba nibẹ pẹlu awọn ọmọ meji, ọkunrin kan ati obinrin kan.

Bakan naa ni wọn ba obinrin alase kan to n dana fun wọn nibẹ, Katherine Onyechi Ngwanma, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), ti wọn si fi panpẹ ofin gbe e.

Lọjọ Aiku tawọn ṣọja lọ sibẹ yii ni wọn doola awon ọmọbirnin keekeeke ti wọn jẹ alaboyun ti wọn to mọkanlelogun, atawọn ọmọ meji ti wọn ba nibẹ.

Lara awọn nnkan ti wọn tun ri ko ninu ile naa ni ẹrọ amunawa (Generator), bẹẹdi alagbeeka ti wọn n ti n gbẹ̀bí alaboyun tabi itọju pajawiri (stretcher), ohun eelo idana gaasi, apo raisi kan, paali tomato alagolo mẹrin, ororo inu ike jala marun-un, gaari apo meji, ohun eelo ọbẹ atawọn nnkan mi-in.

Lieutenant Omale Innocent Prince, ti i ṣe agbẹnusọ ileeṣẹ ologun 14 Brigade, to wa ni Ohafia, ati Oludamọran Gomina Alex Otti lori eto iroyin, Ọgbẹni Ferdinand Okeoma, ni wọn ṣaaju ikọ awọn ṣọja to ya bo ibuba awọn olubi ẹda yii.

Labẹ fidio ti wọn gbe sori ayelujara lawọn ọmọbinrin naa ti jokoo googoogo kaakiri, tawọn ṣọja yẹn si n sọ fun wọn pe ki wọn wọle, ki wọn lọọ palẹ ẹru wọn mọ ni kia.

Ọkan ninu awọn ọmọbinrin naa ti wọn fọrọ wa lẹnu wo to pe ara ẹ ni Divine, lati ijọba ibilẹ Guusu Isiala, nipinlẹ Abia, sọ pe lati bii oṣu marun-un sẹyin loun ti wa nibẹ. Ninu alaye tobinrin naa ṣe nigba ti wọn beere ẹni to mu un debẹ lo ti sọ pe, “Ọga wa kan lo mu mi debi. Nigba ti wọn pade mi loju titi ti mo n rin kiri, wọn beere ibi tawọn obi mi wa, mo si sọ fun wọn pe wọn ti ṣalaisi. Lẹyin naa ni wọn lawọn ni mama kan to le ran mi lọwọ, pe wọn le tọ mi nileewe paapaa, bi mo ṣe tẹle wọn niyẹn. Loootọ wọn ran mi lọwọ lori idanwo aṣekagba iwe mẹwaa ti wọn n pe ni WAEC “.

Lori ọrọ oyun to wa ninu ẹ, o ni toyun-toyun loun debẹ, ati pe ọrẹkunrin oun lo ni in, oun si ti sọ fun un koun too dero inu igbo ti wọn ti ba oun yẹn.

O ni wọn sọ foun pe awọn le oun tọju ọmọ naa. Ọmọbinrin naa ni oun nifẹẹ si ki oun gbe ọmọ naa silẹ ki wọn ba oun tọju rẹ, ki wọn si fun oun lowo.

Ninu alaye Deborah Friday, ẹni ọdun mọkandinlogun (19), toun naa wa ninu oyun, to si tun ni ọmọ ọwọ kan to n tọju lọwọ, o sọ pe iṣẹ telọ tawọn obi oun fi oun si loun n kọ koun too pade bọọda to mu oun debẹ. O loun gbe ọmọ toun loyun le wa nitori baba rẹ ko gba a. Iya to nileeṣẹ naa lo si n tọju oun pẹlu oyun inu atọmọ toun loyun le, oun ko si sọ pe oun fẹẹ ta ọmọ to wa ninu oun ati eyi toun gbe debẹ.

Awọn ikọ yii lawọn ti n sapa lati mu awọn afurasi ti wọn ti fẹsẹ fẹ ẹ, bẹẹ ni wọn fa awọn obinrin mọkanlelogun ti wọn wa ninu oyun, atawọn ọmọ meji ti wọn ri nibẹ le ijọba ipinlẹ Abia lọwọ fun igbesẹ to yẹ.

 

Leave a Reply