Adewale Adeoye
A n pe ọrọ yii lowe, o ti n laro ninu bayii o, pẹlu bi orileede Afrika mi-in, Garbon ṣe tun bọ sọwọ ologun. Awọn ṣọja ilẹ naa ti gbajọba mọ olori orile-ede naa, Ọgbẹni Ali Bongo, ti i ṣe aarẹ alagbada tawọn araalu ọhun dibo yan sipo lọwọ. L’Ojọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii ni wọn kede ni ori tẹlifiṣan pe awọn ti doju ijọba naa bolẹ gẹgẹ bi BBC ṣe sọ.
ALAROYE gbọ pe nibi ikede pajawiri kan, eyi to waye lori ẹrọ tẹlifiṣan orile-ede ọhun lawọn ṣọja kan ti kede iditẹ-gbajoba ọhun, ti wọn si tun sọ pe awọn ti yọwo kilanko Aarẹ Bongo ninu iṣakoso ijọba orile-ede naa loju-ẹsẹ.
Ọgbẹni Bongo yii ni ajọ eleto idibo orile-ede naa kede rẹ pe oun lo tun wọle gẹgẹ bii aarẹ orile-ede naa fun saa kẹta bayii ninu ibo gbogbogboo to waye ni Gabon, laipẹ yii.
Yatọ si pe awọn ṣọja naa ditẹgbajọba lọwọ Bongo, wọn tun lawọn ti wọgi le gbogbo esi ibo awuruju kan ti wọn di lorileede naa patapata.
Bongo ti wọn le danu nipo aṣẹ yii lo ti wa nipo olori orileede ọhun lati ọdun 2009. Saa kẹta si ree ti wọn maa sọ pe oun lo wọle sipo aarẹ.
Bo tilẹ jẹ pe alatako rẹ, Ọgbẹni Albert Ondo Ossa, loun ko fara mọ esi ibo ohun, nitori to sọ pe o lọwọ kan eru ninu, sibẹ, awọn alaṣẹ ajọ eleto idibo orile-ede naa kede Aarẹ Bongo gẹgẹ bii ẹni to ni ibo to pọ ju alatako rẹ lọ.
Lori iditẹ-gbajọba ọhun to waye lorile-ede Gabon, ajọ ‘Economic Community Of West Africa State’ ECOWAS ati ‘Africa Union’ AU ti wọn lodi si iditẹ-gbajọba to waye lorile-ede Niger ko ti i sọrọ lori eyi to waye ni Gabon bayii.
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, paro-paro ni gbogbo aarin ilu lorile-ede naa da, tawọn ṣọja ti wọn ṣẹṣẹ ditẹ gbajọba lọwọ si n lọ kaakiri boya wọn aa ri ẹni to fẹẹ fa wahala kan tabi omiran, ki wọn le ki i mọlẹ, ki wọn si da seria gidi fun un loju-ẹsẹ.