Awọn aṣofin Ogun dabaa pe ki ayajọ ọjọ Iṣẹṣe maa jẹ ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ

Jamiu Abaymi

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun yii, ni ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun dabaa pe ki gbogbo ogunjọ, oṣu Kẹjọ, lọdọọdun, maa jẹ ayajọ ọjọ Iṣẹṣẹ nipinlẹ Ogun.

Lasiko Ijokoo ile, eyi ti  Ọlakunle Oluọmọ to jẹ olori ile naa dari ni wọn ti fẹnu ko pe ki ayajọ ọjọ Iṣẹṣe nipinlẹ Ogun maa jẹ ọjọ isinmi fun awọn oṣiṣe ijọba ati gbogbo eniyan ipinlẹ naa. 

lori ọmọ ile to pọ ju lọ (majority leader), Yusuf Sherif, lo dabaa yii, ti Lukmon Adelẹyẹ, to jẹ ọmọ ile to kere ju lọ (minority leader) si ṣikeji aba naa.

Ọpọlọpọ awọn aṣofin ti wọn fọwọ si aba naa ni wọn tẹnu mọ ọn pe aba naa yoo jẹ ki aṣa ati iṣe Yoruba fẹsẹ mulẹ nipinlẹ Ogun, ti awọn arọmọdọmọ to n bọ lẹyinwa ọla yoo si le jogun ba a. 

Ninu ọrọ tiẹ, Olori ileegbimọ aṣofin naa, Oluọmọ, ni igbesẹ yii yoo jẹ ki ọpọ eeyan ka aṣa Yoruba si nnkan Pataki, o fi kun un pe ijọba apapọ nikan lo le fontẹ lu ki isinmi maa wa ni gbogbo ayajọ ọjọ iṣẹṣẹ nipinlẹ Ogun. 

Leave a Reply