Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Diẹ lo ku kawọn aṣẹwo dana sun ọkunrin kan, Niyi, laarin ọja ọba to wa lagbegbe Ọba Adesida, niluu Akurẹ, lẹyin toun atawọn ọrẹ rẹ kan kọ lati sanwo kinni ti wọn ṣe fun wọn.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Niyi atawọn ọrẹ rẹ meji kan lọ sọdọ awọn agbelepawo ọhun, ti wọn si jọ ṣadehun lori iye ti wọn yoo gba fun kinni aṣemọju ti wọn fẹẹ ṣe.
Awọn ọrẹ Niyi ko fi bẹẹ sun asunwọra ni tiwọn lẹyin ti wọn pari iṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe, ki ilẹ Ọjọruu, Wẹsidee, too mọ ni wọn ti yọ kẹlẹkẹlẹ dide lẹgbẹẹ awọn aṣẹwo ti wọn sun si ti, ti wọn si yara bẹsẹ wọn sọrọ ki awọn oloṣo ọhun too ji.
Ori Niyi to ṣi n sun lọwọ ni wọn fabọ si lẹyin ti wọn ṣakiyesi pe awọn ọrẹ rẹ ti sa lọ lai sanwo iṣẹ ti wọn ṣe, alubami ni wọn kọkọ lu u ninu otẹẹli ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ki wọn too wọ ọ sita gbangba laarin ọja.
Awọn meji ni awọn ọmọ alaṣẹwo ọhun fi afọku igo dara si lara nibi ti wọn ti n gbiyanju ati gba ọkunrin naa silẹ lọwọ wọn.
Awọn ọlọpaa tesan B Difiṣan to wa lagbegbe Oke-Aro, l’Akurẹ, ti wọn rin sasiko ni wọn gba a silẹ lọwọ wọn, ti wọn ko fi raaye dana sun un lọjọ naa.
A gbọ pe gbogbo awọn asẹwo to wa nibi iṣẹlẹ yii lawọn agbofinro naa fi pampẹ ofin ko lọ si teṣan lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.