Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Wahala ati idarudapọ ti ko kere lo ṣẹlẹ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii, lakooko tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa atawọn awakọ ajagbe ti wọn fi n pọn epo bẹntiroolu fija pẹẹta loju ọna to lọ si ilu Ilua ati Sanni Sala, nijọba ibilẹ Onidagbasoke Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ.
Iṣẹlẹ naa waye nigba tawọn aṣọbode to n gbogun ti iwa gbigbe ẹru kọja lọna aitọ ti wọn maa n pe ni Boarder Drill, kọ lu awọn to n ko epo lọna aitọ lọ siluu Ọkẹrẹ lati ilu Ṣaki, eyi to pada ṣokunfa iku eeyan meji, tawọn mi-in tun ṣeṣe yannayanna.
Gẹgẹ bi ọkan lara awakọ epo bẹntiroolu tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, Ọgbẹni Dauda Ayiki, ṣe sọ f’ALAROYE, o ni deede aago meji ọsan ọjọ naa lawọn ikọ Boarder Drill ka wọn mọ ileepo kan laduugbo Kinni-Kinni, nibi ti wọn ti fẹ maa loodu epo lọ sorileede olominira Benin.
O ni gbara tawọn aṣọbode ọhun de ni idunaa-dura waye laarin wọn, ti wọn si gba ẹgbẹrun lọna ọtaleerugba o din mẹwaa Naira (N250,000.00) lọwọ wọn lati fun wọn laaye gbe epo naa kọja.
Ayiki tẹ siwaju pe lẹyin wakati mẹrin ti wọn ti gba owo naa lọwọ wọn, tawọn awakọ naa si ti n ba tiwọn lọ ni wọn ba tun pade awọn ẹṣọ kọsitọọmu yii kan naa ni Abule Ilua ti ko ju nnkan bii kilomita mẹẹẹdọgbọn siluu Ṣaki, ti wọn tun da wọn duro lati tun gba owo mi-in lọwọ wọn. O ni gbogbo alaye awọn ọlọkọ naa pe awọn ti sanwo tẹlẹ ko si yẹ ki wọn tun waa rẹbuu awọn lẹẹkeji lo ja si pabo, bayii ni awuyewuye gbigbona ṣe bẹ silẹ laarin wọn, ko si pẹ tawọn kọsitọọmu naa fi bẹrẹ si i yinbọn.
Ibọn ti wọn n yin ni koṣẹkoṣẹ ọhun lo ni o lọọ ba ọkan lara awọn awakọ naa nikun, tiyẹn si dagbere faye lẹsẹkẹsẹ.
Ọgbẹni Ayiki ni gbara tiroyin iṣẹlẹ naa to awọn araalu leti lo fa a tawọn ọdọ ilu Ṣaki fi yari, ti wọn si waa ṣakọlu sileeṣẹ awọn kọsitọọmu to wa laduugbo Ijale-Ọda, wọn ba awọn ọkọ ayọkẹlẹ kọsitọọmu marun-un jẹ, wọn si ṣeku pa ọkan lara awọn ọga wọn lasiko ifẹhonu han naa lati gbẹsan awakọ ti wọn pa. Yatọ si pe wọn pa ọga kọsitọọmu ọhun, wọn tun fibinu gbe oku rẹ lọ, ko si ti i sẹnikẹni to mọ ibi tokuu naa wa di bayii.
Nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa ni awọn oṣiṣẹ panapana waa pa ina awọn ọkọ kọsitọọmu ti wọn dana sun naa, ṣugbọn paro paro ni gbogbo agbegbe naa da lasiko naa.
Ọga ọlọpaa agbegbe ọhun, SUP Toyin Ẹnisẹyin, ati ọga awọn ọmọ ologun pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ sifu difẹnsi ni wọn duro wamu wamu lati ri i pe wọn dena akọlu mi-in to ba tun fẹẹ yọju.
Ni bayii, oku awakọ naa la gbo pe o ṣi wa ni mọṣuari ileewosan aladaani Tunmiṣe, to wa laduugbo Gẹdu.
Gbogbo akitiyan wa lati ba ọga kọsitoomu ẹka ilu Ṣaki, CSC Shehu Minna sọrọ lo ja si pabo, wọn ni ọga naa wa niluu Ibadan, ṣugbọn Ọkẹrẹ ti ilu Ṣaki, Ọba Khalid Ọlabisi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o si ti paṣẹ ofin konilegbele ọlọjọ mẹta titi di akoko tawọn ọdọ tinu n bi naa yoo sinmẹdọ lori ọrọ ọhun.