Faith Adebọla, Eko
Ko si beeyan ṣe le jẹ ọdaju to, to ba ri i bi awọn eeyan ṣe bara jẹ, ti wọn si n sunkun kikan kikan, ti awọn ọkunrin ti ko le sunkun n mi imi ẹdun, ti oju wọn si pọn kankan, nibi isinku ọkan ninu awọn aṣofin Eko to n ṣoju awọn eeyan Konstituẹnsi Keji, ni Mushin, Họnọrebu Abdul Sobur-Ọlawale, ko si ki tọhun naa ma ṣomi loju.
Awọn aṣofin ipinlẹ Eko ni wọn lọọ gba oku ọkan ninu wọn yii ni ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, to wa ni Ikẹja. Olori ile naa, Mudashiru Ọbasa, lo ṣiwaju wọn. Bakan naa ni ẹgbẹ awọn iyawo awọn aṣofin ipinlẹ Eko, awọn ara, ọrẹ, ojulumọ atawọn to fẹ ti ọkunrin naa wa nibẹ.
Bi wọn ti gba oku naa tan ni wọn gbe e taara lọ si ile rẹ. Niṣe ni ẹkun si n pe ẹkun ran niṣẹ nigba ti wọn gbe Họnọrebu Abdul Sobur-Ọlawale de ile rẹ. Ohun to jẹ ki ọrọ naa ka ọpọ eeyan lara ni pe ki i ṣe pe ọkunrin naa n saisan tẹlẹ, koko ni ara rẹ le ko too gba ilu Jos lọ, nibi ti wọn ti lọọ ṣide eto ipolongo aarẹ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu.
Lẹyin ti awọn mọlẹbi ti foju ri i ni wọn gbe e lọ si itẹkuu Ebony Vaults, to wa ni Ikoyi, niluu Eko, nibi ti wọn ti sin in ni ilana Musulumi.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, Igbakeji rẹ, Babafẹmi Hamzat, wa lara awọn ti wọn ṣiwaju oku naa lọ si itẹkuu ti wọn si in si.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla yii, ni ọkunrin naa ku siluu Jọs, nibi ti wọn ti lọọ ṣide eto ipolongo aarẹ oludije ẹgbẹ APC, Bọla Ahmed Tinubu.
Wọn ni wọn ti dọhun-un layọ atalaafia, eto ipolongo naa si bẹrẹ bi wọn ṣe ṣeto rẹ, ṣugbọn lori iduro toun atawọn yooku rẹ wa, ti wọn ti n kọrin, ti wọn si n da si eto to n lọ ọhun, ni nnkan ti yipada biri fọkunrin naa, wọn lo sọ fawọn ẹgbẹ rẹ pe ooru n mu oun lati inu wa, o si n laagun lakọlakọ.
Ki wọn too ṣẹju peu, wọn lojiji laṣofin yii ṣubu lulẹ, lawọn to wa nitosi rẹ ba gbe e digbadigba, wọn sare gbe e lọ sinu ọkọ agbokuu-gbalaaye kan to wa nitosi lati pese itọju pajawiri fun un, lẹyin naa ni wọn gbe e lọ sileewosan aladaani kan to ko fi bẹẹ jinna sibẹ, ṣugbọn ki wọn too debẹ, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin, ‘O mi titi’ ti lọ.
Ọpọlọpọ ọrọ rere ni wọn n sọ nipa aṣofin naa, wọn leeyan to lawọ, to si fẹran awọn eeyan rẹ ni. A gbọ pe o pese mọto to n gbe awọn akẹkọọ agbegbe idibo re lọ sileewe lọfẹẹ.