Awọn aṣofin buwọ lu miliọnu lọna ẹgbẹrin dọla ($800m) ti Tinubu fẹẹ ya

Monisọla Saka

Awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin atawọn ileegbimọ aṣofin agba, ti fọwọ si ẹyawo ẹgbẹrin miliọnu dọla ($800m), ti Aarẹ Bọla Tinubu, fẹẹ ya lati banki agbaye.

Bẹẹ ni wọn tun buwọ lu ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira, to ni ki wọn foun, lati inu owo ti wọn ti ṣeto silẹ gẹgẹ bo ṣe wa ninu aba eto iṣuna ọdun 2023, ti wọn ka lati inu oṣu Kejila, ọdun to kọja.

Owo yii, ni Tinubu ni awọn yoo fun awọn araalu ti ara n ni, paapaa ju lọ latari owo iranwọ ori epo ti awọn yọ, to si ti ṣe bẹẹ sọ gbogbo nnkan di ọwọngogo.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun yii, lẹyin ti wọn ṣe aṣaro lọ ti wọn ṣe e bọ, lawọn aṣofin fọwọ si ibeere Aarẹ, eyi to ti gbe siwaju wọn lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun yii.

Tẹ o ba gbagbe, ibeere fun ẹyawo lati banki agbaye yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti kọkọ gbe siwaju awọn aṣofin lasiko to ku bii ọsẹ mẹta ti yoo pari saa eto ijọba rẹ ninu oṣu Karun-un, ọdun yii.

Ẹyawo yii ni Tinubu beere fun ontẹ awọn aṣofin lori ẹ, ninu lẹta to kọ si wọn.

O ni, “Mo n kọwe sawọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin lati ba mi buwọ lu atunṣe eto iṣuna ọdun 2023, ti wọn ti gbe kalẹ lati ọdun 2022.

Owo yii ṣe pataki nitori ati le pese awọn nnkan amayedẹrun ti yoo mu adinku ba inira ti owo iranwọ ta a yọ ko ba awọn ọmọ Naijiria.

Ẹẹdegbẹta biliọnu Naira ni a fẹẹ yọ ninu aba eto iṣuna ọdun 2022, lati le pese awọn nnkan amaratuni fawọn araalu”.

Bakan naa ni awọn aṣofin agba naa fọwọ si ẹgbẹrin miliọnu dọla ($800m), ti wọn fẹẹ ya lọwọ banki agbaye.

Owo ti Tinubu fẹẹ ya, tawọn aṣofin si ti jan an lontẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, pe ko gba a yii, lo ni ijọba apapọ fẹẹ lo lati fi ṣe awọn iṣẹ to wa niwaju wọn.

Owo yii ni wọn ni awọn ọmọ Naijiria ti wọn o rọwọ họ’ri bii miliọnu mejila, yoo jẹ anfaani rẹ fun odidi oṣu mẹfa, pẹlu bi ọn yoo ṣe maa fun wọn ni ẹgbẹrun mẹjọ loṣooṣu. Inu banki awọn eeyan ti wọn ba mu yii nijọba ni awọn yoo maa san ẹgbẹrun mẹjọ Naira yii si fun oṣu mẹfa.

Ninu lẹta ti Aarẹ fi ranṣẹ, ti olori ileegbimọ aṣofin agba, Godswill Akpabio, ka si gbogbo ile leti lo ti ni, “Pẹlu inu didun ni mo fi gbe ọrọ yii wa siwaju yin. Mo fẹ kẹ ẹ mọ pe awọn igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ, ti Aarẹ Muhammadu Buhari jẹ adari fun ti gba aṣẹ lati ya ẹgbẹrin miliọnu dọla lati banki agbaye, nitori iṣẹ ijọba, ṣaaju akoko yii.

Bakan naa ni yoo daa kẹ ẹ mọ pe owo ta a fẹ ya yii yoo wa fun ilo awọn ọmọ Naijiria, ati lati ṣeranwọ fawọn alaini, lati le maa gbọ awọn bukaata keekeeke ti wọn ba ni.

“Yoo daa kẹ ẹ tun mọ pe ẹgbẹrun mẹjọ Naira, ni a n gbero lati fi sinu asunwọn awọn ọmọ Naijiria bii miliọnu mejila to ku diẹ kaato fun. Ki ọrọ yii le da yin loju, taara sinu banki wọn ni wọn yoo maa sanwo naa si.

“Eto yii, ni a lero pe yoo mu amugbooro ba eto ọrọ aje wa, ti yoo si tun mu iyatọ nla ba eto ilera, ounjẹ jijẹ, eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan.

Pẹlu gbogbo alaye to wa nilẹ yii, mo n rọ awọn ile igbimọ aṣofin lati ba mi buwọ lu ẹyawo ẹgbẹrin miliọnu Naira ta a fẹẹ ya lati banki apapọ”.

Bayii ni lẹta ti Aarẹ Tinubu kọ sawọn aṣofin ṣe lọ, ni kiakia ti wọn gbe ọrọ naa yẹ wo laarin ara wọn ni wọn si buwọ lu u lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun yii.

Leave a Reply