Awọn Aṣofin Eko fẹẹ ṣeranwọ fawọn to padanu dukia wọn lasiko iwọde SARS

Faith Adebọla, Eko

Ile-igbimọ aṣofin Eko ti lawọn maa ṣatilẹyin ati iranwọ owo fawọn to padanu dukia wọn ninu rogbodiyan SARS to waye lọsẹ mẹta sẹyin nipinlẹ naa. Latari eyi, wọn ti bẹrẹ si i gba aroye awọn ti wọn padanu dukia ati okoowo wọn ninu iṣẹlẹ naa.

Odidi ọjọ mẹta, lati Ọjọbọ, Wẹsidee, si ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni wọn ya sọtọ lati fi gbọ ẹdun ọkan awọn araalu tọrọ kan ni gbọngan apero kan ninu ọgba ileegbimọ aṣofin Eko. Ẹkun idibo sẹnetọ mẹtẹẹta ti Eko pin si ni wọn ya ọjọ kọọkan sọtọ fun.

Olori  ile naa, Ọnarebu Mudaṣiru Ajayi Ọbasa, ẹni ti igbakeji rẹ, Ọnarebu Wasiu Ẹṣinlokun-Sanni, ṣoju fun, sọ pe o pọn dandan lati gbe igbesẹ naa tori obitibiti dukia ati okoowo lawọn eeyan padanu lasiko laasigbo ọhun, ọpọ ninu wọn lo si nilo iranlọwọ lati bẹrẹ ọrọ aje wọn pada.

Ninu ọrọ to ba akọroyin ALAROYE sọ lẹyin apero ọjọ Wẹsidee, Ọnarebu Wasiu ni idi pataki tawọn fi n gbe igbesẹ yii ni pe ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu, niwọn igba ti eyi ko si ti ṣee ṣe doju ami lasiko rogbodiyan SARS to waye ọhun, ijọba ni lati tẹwọ gba ojuṣe adanu to ba waye, ki wọn si wa nnkan ṣe si i.

Ọnarebu Sanni sọ pe lẹyin apero ọjọ kẹta, to ba di ọjọ Abamẹta, Satide, awọn yoo ṣabẹwo sawọn ibi tiṣẹlẹ naa ti waye. Lẹyin eyi lo ni awọn akọṣẹmọṣẹ tawọn ti pese bii awọn eleto ma-da-mi-dofo (Insurance), awọn to n diwọn ile ati dukia (Estate Valuers) atawọn mi-in ti pupọ lara wọn naa wa nikalẹ nibi apero yii, yoo bẹrẹ iṣẹ, wọn yoo si jabọ fun ile. Lẹyin eyi lawọn yoo bẹrẹ si i pese owo iranwọ, eyi ti Ẹṣinlokun ni ko ni i pẹ rara, tori awọn mọ pe ọpọ eeyan maa fẹẹ taja ọdun Keresi ati ipari ọdun to wọle de tan yii.

Oniruuru aroye ati ẹdun ọkan lawọn to wa mẹnuba nigba ti wọn n sọrọ:

Emeka Eze  beere pe bawo nijọba ṣe maa ran awọn tawọn ọlọpaa ti ri lara dukia ati ọja wọn ti wọn ji ko gba pada, ṣugbọn tawọn agbofinro naa kọ lati yọnda rẹ fawọn lẹyin idanimọ.

Abilekọ Ṣade Salami to wa lara awọn to ni Adeniran Ogunsanya Shopping Mall tawọn janduku fọ kanlẹ sọ pe aworan fidio awọn to waa ko oun lẹru wa lọwọ oun, rekete loju awọn janduku naa han bi wọn ṣe n ji ọja oun ko, tori kamẹra to n ka ohun to ṣẹlẹ silẹ wa nileetaja naa. Awọn aṣofin ti gba eda fidio naa silẹ fun iwadii.

Toyin Bakare ati Adeọla Alaka  ni wahala awọn janduku lagbegbe Orile si ọna Bọde Thomas ti di lemọlemọ debii pe awọn olugbe agbegbe naa ko le sun oorun asun-diju mọ. O ni kijọba ṣe geeti nla ti yoo paala sawọn agbegbe yii, tabi ki wọn gbe teṣan ọlọpaa kan wa sibẹ.

Abilekọ Ndidi beere bi ijọba ṣe maa ran awọn ileeṣẹ nla lọwọ, yatọ si tawọn olokoowo keekeeke, to fara gba ninu yanpọnyanrin naa.

Nkechukwu Okafor fẹẹ mọ bi ijọba yoo ṣe ṣeranwọ fawọn kan ti wọn ti n tun ṣọọbu wọn ṣe pada funra wọn, tori o le ma ṣee ṣe fawọn aṣofin naa lati mọ bi adanu wọn ṣe to mọ nigba ti wọn yoo ba fi ṣabẹwo sibẹ lọjọ Abamẹta.

 

Leave a Reply