Ọlawale Ajao, Ibadan
Laarin ọsẹ meji ti wọn da alaga ijọba ibilẹ Irẹpọ, Ọnarebu Sulaimon Lateef Adeniran, duro, ileegbimọ aṣofin Ọyọ tun ti da alaga ijọba ibilẹ onidagbasoke Guusu Isẹyin, Ọnarebu Ajibọla Raheem Fasasi, duro.
Ọnarebu Fasasi, to tun jẹ igbakeji alaga ijọba ibilẹ Isẹyin ni wọn da duro fungba diẹ nitori ẹsun magomago owo tí wọn fi kan an.
Awọn eeyan ijọba ibilẹ Onidagbasoke naa la gbọ pe wọn kọwe ẹsun ta ko o nileegbimọ, wọn ni ni nṣe ni jagunlabi n tu dukia ijọba ta ni gbanjo.
Nigba to n kede idaduro ọhun, Olori awọn aṣofin ipinlẹ naa, Ọnarebu Adebọ Ogundoyin, sọ pe Ọnarebu Fasasi ko gbọdọ de ile ijọba ibilẹ Guusu Isẹyin, bẹẹ ni ko gbọdọ pera ẹ lalaga kansu naa nibikibi.
Lẹyin naa lo gbe igbimọ ẹlẹni meje kan kalẹ lati sewadii nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan alaga ijọba ibilẹ naa.