Awọn aafaa Ilọrin wọle adura, wọn lọdun tawọn oniṣẹṣe fẹẹ ṣe logunjọ, oṣu Kẹjọ, ko ni i ṣee ṣe

L’ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹjọ yii, ni Magaji Nda tilu Ilọrin, Alaaji Salihu Wọru Mohammed, pe awọn Magaji, awọn imaamu ati awọn aafaa jọ, ti wọn ṣe akanse adura lori bi ayajọ ọdun Iṣẹṣe ti wọn maa n ṣe lagbaye ko ṣe ni i waye niluu Ilọrin, gẹgẹ bi awọn ẹlẹsin iṣẹṣe ṣe n gbero lati ṣe ọdun ọhun ninu ilu yii.

Fadilatu Sheikh Alaaji AbdulRazaq Mohammed Jamiu Erubu, lo ṣaaju adura naa ni ilana ẹṣin Musulumi, gbogbo wọn ni wọn si jọ gbohun adura wọn soke si Ọlọrun Allah, pe ki awọn awọn onisẹse maa le wọ ilu Ilọrin, logunjọ, oṣu Kẹjọ yii, gẹgẹ bi wọn ṣe n gbero lati darapọ mọ ọgọọrọ awọn ẹlẹsin Iṣẹṣe jake-jado agbaye lati kopa ninu ayajọ tọdun 2023 yii.

Ki adura too bẹrẹ ni Magaji Nda ti sọ idi ti wọn n tori ẹ gbe adura naa kalẹ. Ninu ọrọ rẹ, o ni idi ti gbogbo awọn Magaji, awọn imaamu, atawọn ọmọ ilu fi jokoo adura ni pe awọn ko fẹ ki ọdun Iṣẹṣe waye niluu Ilọrin, ki ogun to ti ṣẹ maa tun gberi mọ.

O tẹsiwaju pe ilu alaafia ni ilu Ilọrin, ọba akọkọ to si kọkọ jẹ n’llọrin, AbdulSalam lorukọ rẹ n jẹ, eyi to tumọ si alaafia. Eyi lo ni alaafia fi n jọba tipẹ-tipẹ. O ni, ‘Alimi ti ṣẹgun awọn ẹlẹbọ, a si ti ṣekilọ pe awọn ẹlẹbọ ko gbọdọ wọ Ilọrin, ṣugbọn ti wọn ba sọ pe awọn yoo wọ Ilọrin ni dandan, wọn aa jiyan wọn niṣu, ati pe awọn to dan an wo lọjọsi, wọn parẹ ni, ti wọn ba gbera ti wọn o parẹ loju ọna, ti wọn ba wọ Ilọrin, wọn aa parẹ patapata ni’’.

O ni ọkunrin kan wa to n pe ara rẹ ni Talọlọrun, Ọlọrun yoo fi ara rẹ han an laipẹ, ibọ igi, bọ erupẹ, ki wọn ma gbe e de ilu Ilọrin, tori pe Ilọrin ki i ṣe ilu ẹlẹbọ.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o rọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahaman AbdulRazaq, ko ma gba akojọpọ awọn ẹlẹsin iṣẹṣe laaye lati ṣọdun iṣẹṣe wọn logunjọ, oṣu Kẹjọ yii.

Leave a Reply