Awọn adigunjale fi Aliyu duro, ni wọn ba ji ọkada gbe lọ n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọrọ ti a ko mọwọ mẹsẹ, afi ka maa gbadura ko ma jẹ tiwa, k’Ọlọrun ma si jẹ ka jiya aimọdi, nitori iya aimọdi lo n jẹ ọmọkunrin kan, Umaru Aliyu, lọwọ bayii. Ọrọ ti ko mọ ohunkohun nipa rẹ lo tori ẹ dero kootu. Iran wiwo lo ko ba a. Awọn adigunjale ni wọn fi i duro lọdọ ẹni ti wọn fẹẹ ra ọkada lọwọ rẹ, ni wọn ba ni awọn fẹẹ tẹẹsi ọkada naa lọ, ọmọkunrin ti wọn fi duro naa ko si gbọ ohun ti wọn n wi, bi awọn atilaawi ṣe gbe ọkada sa lọ niyẹn, ni ọlọkada ba di Aliyu mu.

Arakunrin kan to n ta ọkada lo wọ Aliu lọ si kootu ibilẹ kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Ẹṣun ti wọn fi kan an ni pe Aliyu atawọn eeyan rẹ waa ra ọkada lọwọ rẹ, ni awọn yooku ba gun ọkada naa lọ, wọn lawọn fẹẹ tẹẹsi rẹ lọ wo, wọn ni ki Aliyu duro de awọn. Titi di bi a ṣe n ko iroyin yii, awọn eeyan yii ko pada wa mọ pẹlu ọkada ti wọn gbe lọ. Ẹni to n ta ọkada ni Aliyu gbọdọ san owo ọkada naa tori pe wọn jọ waa ra a ni.

Ṣugbọn Aliyu sọ fun kootu pe oun ko mọ awọn to gbe ọkada naa lọ ri rara, kọda oun ko rin pade wọn ri laye, o ni oun kan duro ni toun nigba ti wọn n dunaadura ọkada ti wọn fẹẹ ra ni, ati pe oun ko gbọ ede Yoruba ti wọn n sọ, tori pe ede Hausa loun gbọ.

Onidaajọ Lawal, pasẹ ki wọn ju Aliyu sọgba ẹwọn Oke-Kura, o sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, osu Kejila, 2022.

Leave a Reply