Awọn adigunjale fọ banki niluu l’Okuku, wọn kowo nla lọ

Florence Babaṣọla

 

Lọwọlọwọ bayii, awọn ọlọpaa ati ọmọ ẹgbẹ OPC ti n dọdẹ awọn adigunjale ti wọn kọ lu ileefowopamọ kan niluu Okuku, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin.

Lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lawọn adigunjale ti ko ti i sẹni to mọ iye wọn ọhun ya wọ ilu Okuku pẹlu ibọn to n dun lakọlakọ, ti wọn si ko obitibiti owo ninu banki kan nibẹ.

Alukoro ọlọpaa, SP Ọpalọla, sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, lo ṣaaju awọn ọlọpaa ti wọn n dọdẹ awọn adigunjale naa lọ bayii.

Bakan naa ni Alakooso OPC l’Ọṣun, Deji Aladeṣawẹ, sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oun naa ti darapọ mọ awọn ọlọpaa lati le wọn lọ nitori awọn gbọ pe ọna Iba ni wọn gba lọ lẹyin ti wọn fọ banki naa tan.

Leave a Reply