Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Pẹlu bo ṣe jẹ pe alaafia ko fi bẹẹ to fun Kẹmi Afọlabi Adeṣipẹ, oṣere tiata Yoruba to kede ohun to n ṣe e faye lọsẹ to kọja yii, ṣibẹ, obinrin naa tun ko sọwọ awọn adigunjale lọdun tuntun yii. Wọn ṣa a ladaa lapa, wọn tun gba awọn foonu rẹ atawọn nnkan mi-in lọ.
Kẹmi funra ẹ lo fiṣẹlẹ naa lede loju opo Instagraamu ẹ. O ni oko fiimu loun lọ l’Arepo, nipinlẹ Ogun, oun si wa ninu mọto oun pẹlu dẹrẹba to n wa mọto naa, afi bawọn adigunjale ṣe ya bo awọn lojiji.
Oṣere yii sọ ọ di mimọ pe sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ wa loju ọna ọhun nigba tawọn ole naa kọ lu oun ati dẹrẹba. O ni wọn fọ gilaasi mọto oun, bẹẹ ni wọn fi ada ṣa oun lapa, wọn ko foonu oun lọ, wọn si fọ dẹrẹba oun naa lori.
O ni bi wọn ṣe ṣọṣẹ wọn tan ni wọn sa lọ, ti gbogbo ara oun bo yẹlẹyẹlẹ latari gilaasi ti wọn fọ naa, oun ko si ti i foju kan oorun latigba tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, nitori ibẹru ti kinni naa ko sọkan oun.
Kẹmi fi kun un pe ohun to ṣẹlẹ yii tubọ fidi ẹ mulẹ pe aabo ko si ni Naijiria yii, beeyan si fi gbogbo ọjọ pariwo fawọn olori wa pe ẹmi araalu ko de, wọn ki i dahun, niṣe ni wọn n kọti ikun si ariwo araalu, ti wọn ki i ja alaafia wọn kunra.
Nitori ẹ lo ṣe fi iṣẹlẹ naa lede to si fi orukọ Sanwo-Olu si i, o fi tawọn ọlọpaa Naijiria ati ti Aarẹ Muhammadu Buhari si i, o ni ki wọn maa ri i bo ṣe n lọ.
Pẹlu gbogbo eyi ṣa, obinrin naa sọ pe ole to ja oun ko to nnkan kan ninu ohun toun ti la kọja laipẹ yii, bo si ti le wu ko buru to, Kẹmi loun yoo maa fọpẹ f’Ọlọrun to n da ẹmi oun si ni.