Awọn adigunjale pa ọlọdẹ lẹyin ti wọn ko ọja rẹpẹtẹ ninu ṣọọbu to n ṣọ l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Osogbo

Ọkunrin ọlọdẹ kan torukọ rẹ n jẹ Matthew Ọlalekan lawọn eeyan agbegbe Tecnical, loju-ọna Iwo/Ibadan, niluu Oṣogbo, deede ba oku rẹ niwaju ṣọọbu to n sọ nidaaji Ọjọbọ, Tọsidee, nibi ti awọn adigunjale pa a si.

Nidojukọ ileewe ẹkọṣẹ ọwọ, iyẹn, Osogbo Technical College, Iwo Road, Osogbo, la gbọ pe ṣọọbu ti wọn ti n ta ẹru awọn ọmọde ti oloogbe naa n ṣọ wa.

Oru Ọjọbọ mọju ọjọ Eti la gbọ pe awọn adigunjale naa lọ sibẹ, ti wọn si ko awọn nnkan olowo iyebiye bii goolu, ẹrọ to n fun foonu lagbara, ibusun ọmọde ati bẹẹ bẹẹ lọ lẹyin ti wọn pa ọkunrin ọlọdẹ naa tan.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe obinrin kan, Baṣirat lo lọ si agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Dada Estate, lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti laaarọ Ọjọbọ.

O ni awọn ẹrọ to n fun foonu lagbara (power bank) to jẹ tilẹ okeere bii ọgọrun-un ti owo wọn jẹ miliọọnu mẹta ataabọ naira, goolu ati awọn ibusun ọmọde ti wọn ko ti i mọ iye rẹ lawọn adigunjale naa ko lọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ọmọ ogoji ọdun ni Ọlamilekan ti awọn adigunjale naa pa, awọn ọlọpaa si ti gbe oku rẹ lọ si UNIOSUN Teaching Hospital, fun ayẹwo.

Ọpalọla fi kun un pe ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran yoo bẹrẹ iṣẹ lori iṣẹlẹ naa laipẹ lati le tụsu desalẹ ikoko lori ẹ.

 

Leave a Reply