Gbenga Amos, Ogun
Yooba bọ, wọn loju ina kọ lewura n hu irun, ere buruku lawọn adigunjale kan sa kọwọ awọn agbofinro to n le wọn ma baa tẹ wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lagbegbe Ado-Odo, Ọta, ipinlẹ Ogun, ibi tọrọ naa si ka wọn lara de, niṣe ni wọn sọ ibọn ọwọ wọn danu, wọn o le duro gbe ọkada ti wọn gbe wa, bẹẹ ni wọ o roju ko awọn dukia mi-in ti wọn ji bi wọn ṣe n sare asa-fori-sọ’ganna lọ.
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Sọji Ganzallo o fi ṣọwọ s’Alaroye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji iṣẹlẹ yii, o ni niṣe lawọn ọmọọṣẹ oun lati ẹka Mupin ati Agbara n ṣe patiroolu wọn kiri ilu gẹgẹ bii aṣa wọn, ṣugbọn bi wọn ṣe yọ si adugbo kan ti wọn n pe ni Gasline, nijọba ibilẹ Ado Odo/Ọta, wọn kẹẹfin awọn afurasi ọdaran kan ti wọn fẹẹ gun ọkada ti wọn gbe wa, wọn si ko awọn dukia kan sinu baagi, ti irin ẹsẹ wọn ati irisi wọn mu ifura lọwọ.
Wọn ni bawọn eeyan yii ṣe gboju soke ti wọn ri i pe ọkọ awọn So-Safe lo wa niwaju wọn bayii, afi bii igba ti ekute ri ologinni, niṣe ni wọn ki ere buruku mọlẹ, ẹṣin n yaju ni, bi wọn si ṣe n sare naa ni wọn n da ẹru ọwọ wọn silẹ, bẹẹ lawọn ẹṣọ So-Safe gba fi ya wọn, wọn le wọn, ẹsẹ wọn ko balẹ lati Gasline de ibi kan ti wọn n pe ni Arobiẹyẹ.
Asẹyinwa-asẹyinbọ, awọn alọ-kolohun-kigbe ẹda naa na papa bora, wọn o ri wọn mu, amọ wọn ri awọn ẹru ti wọn ju silẹ ṣa jọ.
Lara awọn ẹru ole ti wọn gba lọwọ wọn ni ọkada Bajaj pupa ọṣaara kan ti nọmba rẹ jẹ TRE 231 VT, ibọn agbelẹrọ pompo kan, ẹnjinni ọili ọkọ, aṣọ, bata, ọti ẹlẹridodo Five alive ati oogun abẹnugọngọ oriṣiiriṣii.
Ganzallo lawọn ti fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti, awọn si ti ko gbogbo ẹsibiiti ti wọn ri gba ọhun le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Onipaanu lọwọ.
O lawọn o ni i ye dọdẹ awọn afurasi yii titi ti wọn yoo fi ri wọn mu.