Jamiu atawọn ọrẹ ẹ ṣa Akinọla pa sile ounjẹ l’Alapẹrẹ

Faith Adebọla, Eko

Iku gbigbona, iku oro, lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan fi pa ọdọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Akinọla Ayegbusi, nigba ti wọn ka a mọnu ile ounjẹ kan to wa lagbegbe Alapẹrẹ, nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, nipinlẹ Eko, lọjọ keje, oṣu Keje, ọdun yii. Jamiu Rasheed, ẹni ọdun mejilelogun, atawọn ẹmẹwa rẹ ni wọn ṣiṣẹ laabi ọhun, wọn ko kumọ, aake ati ada bo Akinọla, wọn si pa a loju ẹsẹ bii ejo aijẹ, ṣugbọn ọwọ ti ba wọn.

Ba a ṣe gbọ, wọn lawọn ọdaran to ṣiṣẹ laabi yii jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Klansman, lawọn, ati pe awọn ti n dọdẹ oloogbe naa tipẹ, wọn lọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ loun naa, wọn lo wa lara awọn to yinbọn pa olori ẹgbẹ awọn lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun to kọja. Atigba naa ni wọn ti  dọdẹ ẹ kiri lati gbẹsan lara ẹ, kawọn too ka a mọnu ile ounjẹ lọjọ ti wọn pa a.

Bi wọn ṣe ri i pe ẹmi ti bọ lara oloogbe naa lawọn oṣika tan tẹsẹ mọrin ẹda wọnyi ti bẹ jade, wọn lọọ sapamọ. Ṣugbọn kamẹra atanilolobo to wa nile ounjẹ naa n ṣiṣẹ lọwọ lasiko iṣẹlẹ yii, oun lo rikọọdu gbogbo ohun to ṣẹlẹ, ọpẹlọpẹ kamẹra yii lo ran awọn ọlọpaa lọwọ ti wọn fi ri awọn ọdaju apaayan naa mu lẹyin oṣu kan aabọ ti wọn ti n sa kiri.

Ninu fọran fidio naa, eyi ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, fi ṣọwọ s’ALAROYE, o ṣafihan bi Akinọla ṣe kọkọ gbiyanju lati sa mọ awọn to fẹẹ pa a lọwọ, lẹyin ti wọn ti bọ ẹwu rẹ, to si ti jajabọ, ṣugbọn o kọsẹ, wọn si le e mu, nibi to ti n rababa lati dide ni wọn ti yọ ada ati aake ti i, ti wọn bẹrẹ si i ṣa a bii igba tawọn alapata n ṣa maaluu lodo ẹran, wọn pa a patapata. Ẹyin eyi ni wọn tun yọ foonu apo rẹ, ọkan ninu wọn si tun yinbọn fun un lẹẹmeji, ni wọn ba bẹ jade, ọrọ si di bo o lọ o yago fawọn to n jẹun lọwọ nile ounjẹ naa, ẹni ori yọ o dile.

Lẹyin iwadii awọn ọlọpaa, awọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ si i tọpasẹ awọn oniṣẹẹbi yii, ọwọ si ba Jamiu ati Sheriff Mọdule, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, ti wọn loun lo n ba wọn tọju nnkan ija wọn pamọ, ibọn meji ni wọn ba lọwọ rẹ, bẹẹ ni wọn tun mu Emmanuel Samson, wọn lọmọ ẹgbẹ okunkun pọmbele loun ni tiẹ.

Wọn lawọn afurasi ọdaran yii ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn, awọn si lọwọ ninu iku Akinọla to waye ọhun.

Hundeyin ni iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, awọn tọwọ ba si ti wa lakata ẹka to n gbogun ti ṣiṣe ẹgbẹkẹgbẹ ati iwa ọdaran abẹle nileeṣẹ ọlọpaa Eko, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi, ṣe paṣẹ.

Wọn lawọn ọtẹlẹmuyẹ ṣi n ba iṣẹ lọ labẹnu lati ṣawari gbogbo awọn amookunṣika to ṣẹgbẹ buruku nipinlẹ Eko.

 

Leave a Reply