Faith Adebọla
Bawọn ologun ati ẹṣọ alaabo ṣe n ge awọn janduku afẹmiṣofo to n fojoojumọ ṣoro bii agbọn lapa Oke-Ọya ilẹ wa lọwọ, lawọn agbebọn yii n bọ oruka, pẹlu bi wọn tun ṣe ṣakọlu lopin ọsẹ yii si ipinlẹ Katsina ati Zamfara, nibi ti wọn ti fiku oro pa eeyan ti ko din ni mẹtadinlogoji, ti wọn si ji eeyan bii aadọta gbe wọgbo lọ.
Oru ọjọ Ẹti, Furaidee, mọju Satide ni wọn lawọn apaayan ti wọn gun ọkada bii ọgọrun-un wa naa ya bo awọn abule to wa lagbegbe ilu Rijiya, nijọba ibilẹ Gusau ati Tsafe, nipinlẹ Zamfara. Bi wọn ṣe debẹ ni wọn ṣina ibọn bolẹ lakọlakọ, eyi si da jinnijinni bo awọn olugbe agbegbe naa ti wọn n sun lọwọ, ni kaluku ba bẹrẹ si i sa asala fẹmi-in wọn.
Awọn afẹmiṣofo naa kọ lu abule Nasarawa Mai Fara, nijọba ibilẹ Tsafe, kan naa, bẹẹ ni wọn tun de agbegbe Dandundun pẹlu.
Eeyan mẹwaa la gbọ pe wọn pa ni Nasarawa Mai Fara, wọn si ko awọn yooku ti wọn ri mu lọ, awọn obinrin ati ọmọde lo pọ ju ninu wọn. Nigba tilẹ yoo fi mọ, iye oku eeyan ti wọn ri ṣa jọ ko din ni ogun.
Titi dasiko yii lawọn ọlọdẹ ṣi n wa awọn oku kaakiri igbo agbegbe naa, tori ko sẹni to le sọ pato boya awọn eeyan ti wọn n wa naa ti wa lara awọn ti wọn ji ko, tabi wọn ti yinbọn pa wọn sinu igbo.
Bi iṣẹlẹ eyi ṣe n lọ lọwọ ni Zamfara, bẹẹ lawọn agbẹbọn mi-in n da ẹmi awọn eeyan legbodo labule Yar Katsina, nijọba ibilẹ Bungudu, nipinlẹ Katsina.
Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe ọpẹlọpẹ bawọn ẹṣọ fijilante agbegbe naa ṣe duro lati gbeja awọn eeyan wọn, o ni eyi ni ko jẹ kiye eeyan to ba iṣẹlẹ akọlu naa rin ju mẹtadinlogun lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, SP Mohammad Sheu fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn akọlu naa waye, ṣugbọn awọn o ti i le sọ pato iye eeyan to ku ati iye ti wọn ji gbe.
Wọn ni ilu Karfi, nijọba ibilẹ Malumfashi, ni Katsina, lawọn apaayan naa ti fẹmi eeyan mẹtadinlogun ọhun ṣofo.
Ọnarebu Aminu Ibrahim Saidu to n ṣoju awọn eeyan Malumfashi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o loun ti ṣabẹwo sagbegbe ti wọn ṣakọlu si naa, oun si ba awọn eeyan tọrọ kan kẹdun. O tun ṣeleri pe eto ti n lọ lati doola ẹmi awọn ti wọn ji gbe.