Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn agbebọn ya bo ileegbe aafaa kan, Alaaji Tunde Aribidesi, lagbegbe Alubarika, ni Gaa-Osibi, niluu Ilọrin, niṣe ni wọn du u bii ẹran, wọn si ji awọn ọmọ rẹ meji gbe lọ.
ALAROYE gbọ pe ni oru ọjọ Abamẹta mọju ọjọ Aiku, ni awọn agbebọn naa lọọ ka a mọle, nigba ti ko silẹkun fun wọn ni wọn fibọn fọ gilaasi ferese wọle, wọn fi ọbẹ du Ọkunrin naa bii ẹran, ṣugbọn iyawo sapamọ, wọn ko ri i, ni wọn ba ko meji to dagba ju ninu awọn ọmọ wọn mẹrin lọ.
Nigba ti ALAROYE de ile oloogbe naa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ko si ẹnikankan nile, sugbọn awọn araadugbo to ba akọroyin wa sọrọ ṣalaye pe ọmọ mẹrin ni aafaa yii bi, awọn agbebọn si ti gbe meji to dagba ju lọ, bẹẹ ni wọn mu foonu aafaa yii paapaa lọ. Lẹyin ti wọn ti ji awọn ọmọ naa gbe sa lọ ni wọn pe mọlẹbi wọn pe ki wọn lọọ mu miliọnu mẹwaa Naira wa ti wọn ba mọ pe awọn fẹẹ gba awọn ọmọ naa laaye.
Titi ti a fi pari akojọpọ iroyin yii, inu ibanujẹ ni gbogbo mọlẹbi Alaaji Tunde wa, ti wọn si n wa owo ti wọn yoo fi doola ẹmi awọn ọmọ to wa ni akata awọn ajinigbe.