Awọn agbebọn gba miliọnu mẹfa Naira owo itusilẹ, wọn tun mu awọn to gbe owo lọ silẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Inu ibanujẹ ni mọlẹbi awọn agbẹ meji kan; Samuel Ọladọtun ati Fashọla Tobilọba, ti awọn agbebọn ji gbe niluu Ileogbo, nipinlẹ Ọṣun, lọsẹ to kọja wa bayii, pẹlu bi awọn ẹruuku ọhun tun ṣe mu awọn ti wọn gbe owo itusilẹ lọ silẹ.

A oo ranti pe Alaroye fi to yin leti pe miliọnu mẹwaa Naira lawọn agbebọn naa beere lọwọ awọn mọlẹbi agbẹ mejeeji nigba ti wọn pe mọlẹbi ọkan lara wọn.

A gbọ pe awọn mọlẹbi mejeeji ko miliọnu mẹfa Naira jọ, awọn agbebọn naa si sọ pe ki wọn gbe owo naa lọ si aala ipinlẹ Kwara ati Kogi, ni ilu Ẹpẹ.

Bi awọn mẹtẹẹta ṣe debẹ lawọn agbebọn naa tun mu wọn silẹ, ti wọn si pe awọn mọlẹbi wọn pe ki wọn gbe miliọnu mẹrinlelogun Naira wa fun itusilẹ wọn.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Royal Ambassador ti awọn ti wọn ji gbe yii wa nileejọsin Baptist, Ọlanihun Zechariah, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni ibanujẹ nla lo jẹ fawọn pe o ti di eeyan marun-un lakata awọn ajinigbe naa bayii.

Ọlanihun ke si gbogbo awọn ọmọ ijọ naa lati gbohun soke lohun rara ke pe Ọlọrun fun itusilẹ wọn.

Ni bayii, gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, ti sọ nipasẹ agbẹnusọ rẹ, Ọlawale Rasheed, pe gbogbo igbesẹ to tọ nijọba ti bẹrẹ si i gbe lati gba itusilẹ awọn maraarun.

Adeleke fi da awọn mọlẹbi wọn loju pe oun ko ni i kaaarẹ titi ti awọn eeyan ọhun yoo fi di riri layọ ati alaafia.

Leave a Reply