Ọlawale Ajao, Ibadan
Kọlukọlu ijinigbe to n ṣẹlẹ lemọlemọ nipinlẹ Ọyọ lẹnu ọjọ mẹta yii ti kan olori ọdọ fẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), Ọgbẹni Isiaka Salawu, pẹlu bi awọn agbebọn ṣe ji iyawo ẹ to n jẹ Dokita Aderiyikẹ Oni-Salawu gbe.
Kayeefi ibẹ ni pe niṣeju ọkọ ẹ bayii ni wọn ṣe wọ ọ ju sinu mọto, ti wọn si gbe e sa lọ tefetefe.
Lati ibi iṣẹ la gbọ pe obinrin naa ti n bọ lalẹ ọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii, ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde, ti awọn ọbayejẹ eeyan ti ẹnikẹni ko ti i mọ bayii fi da a lọna pẹlu ibọn lọwọ laduugbo Aromọlaran, lọna Gbagi, n’Ibadan, ti wọn si ji i gbe lọ.
Wọn ni ọkọ agbokuu-gbalaaarẹ (anbulansi), to jẹ ti ileewosan to ti n ṣiṣẹ lo n gbe e lọ sile, ti ọkọ ẹ si n wa ọkọ ayọkẹlẹ tiẹ tẹlẹ e lẹyin.
Awọn mejeeji ti dele. Nibi ti iyawo si ti sọ kalẹ lati ṣilẹkun abawọle ile wọn ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọhun, lawọn ẹruuku yọ si i, ti wọn si palẹ ẹ mọ lọgan.
ALAROYE gbọ pe bi awọn kan ṣe di iya naa mu, ti wọn n gbe e lọ sinu mọto wọn, lawọn yooku lọọ ba ọkọ, ti wọn si n rọjo iya le e lori ki wọn too gba ẹrọ ibanisọrọ ọwọ ẹ ko ma baa le ribi pe awọn agbofinro.
Akitiyan lati fidi iroyin yii mulẹ lọdọ DSP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko seso rere pẹlu bi ọkunrin naa ko ṣe gbe ipe akọroyin wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.