Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ yii, lawọn agbebọn ji Lukman Ibrahim ti ọpọ eeyan mọ si (Luktech) gbe ni ilu Ojoku, nitosi Ọffa, nipinlẹ Kwara, ti wọn si tun yinbọn pa iyawo rẹ to wa ninu oyun.
ALAROYE gbọ pe Lukman lọ si ṣọọbu rẹ lati aarọ kutukutu ọjọ Abamẹta, Satide, to si n dari pada bọ wale lalẹ pẹlu iyawo rẹ. Afi bi awọn agbebọn ṣe da wọn lọna ni opopona Ojoku, ti wọn si yinbọn pa iyawo rẹ nifọna-fọnṣu. Ni kete ti wọn pa iyawo rẹ tan ni wọn tun ji Lukman gbe sa lọ.
ALAROYE gbọ pe iyawo tawọn ajinigbe ọhun ṣeku pa wa ninu oyun, ti ko si ni i pẹẹ bimọ mọ.
Wọn ti gbe oku arabinrin ọhun lọ si mọṣuari to wa ni ọsibitu kan niluu Ọffa. Titi di igba ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, wọn ko ti i kofiri awọn ajinigbe ọhun.