Monisọla Saka
Ọjọ buruku eṣu gbomi mu ni aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kejila yii, ọdun yii, jẹ fun awọn olugbe adugbo Okoroda, Ughelli, nipinlẹ Delta, pẹlu bi awọn agbebọn kan ṣe deede ya wọnu ile ijọsin awọn Musulumi, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn leralera, lẹyin eyi ni wọn ji awọn mẹta kan gbe lọ nibẹ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ akoroyin jọ ilẹ wa (NAN) ṣe ṣalaye, o ni ni nnkan bii aago meje aarọ ku iṣẹju mẹtala (6:47am), iyẹn lasiko tawọn Musulumi n kirun aarọ lọwọ ni mọṣalaṣi nla to wa l’Opopona Okoroda, Ughelli, lawọn eeyan naa ya bo wọn.
Ọkunrin to pe ara ẹ ni Larry to ba akọroyin NAN sọrọ sọ pe iro ibọn to n ro lakọlakọ ati igbe ẹkun awọn eeyan to n tinu mọṣalaaṣi wa lo ji awọn olugbe adugbo naa silẹ.
O ni, “Larry lorukọ mi, ọkọ ero ni mo n wa fi ṣiṣẹ ṣe ni Ughelli nibi. Itosi mọṣalaṣi yii ni ile ti mo n gbe wa. Ojiji la bẹrẹ si i gbọ didun ibọn ni nnkan bii aago meje aarọ kutukutu ku iṣẹju mẹẹẹdogun, lati inu mọṣalaṣi yẹn, Ṣugbọn ibẹrubojo ko jẹ ki ẹnikẹni ninu ile wa le jade bọ sita bi ile wa ṣe sun mọ ibẹ to, oju windo la ti rọra n yọju. Bi iro ibọn yẹn ṣe n lọọlẹ bayii la n gbọ igbe ẹkun awọn olujọsin ọhun”.
O ni lẹyin tawọn agbebọn naa lọ lawọn eeyan too ribi rọ wọ inu ile ijọsin naa lati wo ohun to n ṣẹlẹ. O lawọn eeyan yii naa ni wọn gbe awọn to fara gbọgbẹ jade, o fi kun un pe awọn eeyan tori ko yọ lọwọ iku airotẹlẹ yii ṣeṣe kọja afẹnusọ.
Awọn olujọsin naa sọ fawọn araadugbo pe awọn agbebọn naa ti ji mẹta ninu awọn gbe lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe eeyan mọkanla lawọn eeyan ti wọn ṣeṣe nibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn kop mẹnu ba awọn mẹta ti wọn lawọn agbebọn ji gbe lọ lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si wọn tan. O ṣeleri pe oun yoo ṣewadii lori ẹ . O ni, “Mo ṣẹṣẹ pe ọga ọlọpaa teṣan Ughelli tan ni, ohun to si sọ fun mi ni pe eeyan mọkanla ni wọn fara gbọgbẹ nibi ikọlu naa. Amọ ṣa, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, a o si ni i jẹ ki eti yin di ba a ba ṣe n ri awọn ọdaran naa mu”.
O ni, lọwọlọwọ bayii, awọn ko ti i ri ẹnikẹni mu, ṣugbọn ọwọ awọn yoo tẹ gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu iṣẹ ibi naa pata.