Awọn agbebọn ji ọmọleewe rẹpẹtẹ ko lọ

Faith Adebọla

Ko ti i sẹni to mọ pato iye wọn o, amọ wọn ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ọmọleewe ti ko di n ni aadọta ni wọn ti toko iroko doko irokoto bayii, awọn agbebọn lo ji gbe laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu Kin-ni, ọdun 2023 yii, niluu Alwaza, nipinlẹ Nasarawa.

Alaroye gbọ pe lasiko tawọn ogowẹẹrẹ naa n lọ sileewe ijọba, LGEA Primary School, to wa niluu Alwaza, nijọba ibilẹ Doma, nipinlẹ Nazarawa, lowurọ ọjọ Furaidee yii ni wọn ji wọn ko. Ṣe awọn ọmọ wọnyi ko kuku mọ pe awọn afurasi ajinigbe kan ti lugọ de wọn lọna ti wọn n gba lọ, wọn ni lojiji ni wọn yọ si wọn pẹlu ibọn, ti wọn si bẹrẹ si i gbe wọn gori awọn ọkada rẹpẹtẹ ti wọn gbe wa.

Wọn ni bawọn majeṣin ọhun ṣe kọwọọrin lati wọ geeti ileewe wọn ni wọn ko wọn wọgbo, ko si sẹnikẹni to da wọn lọwọ kọ titi ti wọn fi ko wọn lọ sinu aginju ọhun.

A o ti i gbọ pawọn afẹmiṣofo yii pe ẹnikẹni lori aago lati sọ ohun ti wọn yoo gba ki wọn too tu awọn ọmọọlọmọ yii silẹ, bẹẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ni awọn ṣẹṣẹ n gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni, wọn lawọn maa ṣewadii, awọn yoo si fi atẹjade lede nipa ẹ laipẹ.

Tẹ o ba gbagbe, leralera lawọn janduku afẹmiṣofo ji ọgọọrọ awọn akẹkọọ ileewe pamari ati sẹkọndiri gbe lagbegbe Oke-Ọya lọdun 2020 si 2022 to lọ yii, obitibiti owo si ni wọn gba ki wọn too tu awọn ti wọn  mu londe silẹ.

 

Leave a Reply