Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n koroyin yii jọ lọwọ, awọn ọlọpaa agbegbe kan ti wọn n pe ni Alfa, ni Igbogbo, niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko, ṣi n wa awọn tọkọ-taya kan tawọn agbebọn ji gbe sa lọ lopin ọsẹ to kọja yii. Bẹẹ lo jẹ pe awọn agbebọn ọhun ko ti pe awọn mọlẹbi awọn ẹni ti wọn ji gbe lati sọ ohun ti wọn n fẹ lọwọ awọn eeyan wọn ko too di pe wọn aa ju wọn silẹ.
Ṣe lọrọ ọhun di bo o lọ yago fun mi ni aṣaalẹ ọjọ Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, nigba tawọn agbebọn kan bẹrẹ si i yinbọn soke gbau lati fi da ipaya ati ibẹru bojo saarin awọn olugbe agbegbe naa, kawọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti ji awọn tọkọ-taya kan gbe lọ.
Ọgbẹni Adisa to jẹ olugbe agbegbe naa to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ko sẹni to mọ pe wọn fẹẹ ji awọn tọkọ-taya ọhun gbe sa lọ, iro ibọn ọhun po ju lọjọ naa, nigba ti ariwo ibọn ọhun lọ silẹ tan tawọn eeyan jade sita la too mọ pe wọn ti ji awọn tọkọ-taya kan gbe sa lọ, ọmọ awọn ẹni ti wọn ji gbe yii lo sọ pe inu igbo kekere kan lawọn ajinigbe naa gbe awọn obi rẹ gba. Ṣugbọn ko pẹ rara tawọn ọdaran naa pari iṣẹ ọwọ wọn tan tawọn ọlọpaa fi de saduugbo naa lati fọwọ ofin mu awọn eeyan ọhun. Ṣugbọn ti wọn ko ri awọn ẹni ibi naa mu nitori gbogbo inu igbo tọmọ yii sọ pe wọn gba ni wọn fọ pata, ti wọn ko ri ẹnikankan nibẹ.
Ṣa o, awọn ọlọpaa ọhun pada fọwọ ofin mu ọmọ ijọ Sẹlẹ kan to n wẹ iwẹ odo lọwọ nigba ti wọn ba a lẹnu iwẹ naa ati awọn kọọkan ti wọn ri lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Gbogbo akitiyan awọn oniroyin lati fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ lọdọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko lo ja si pabo.