Awọn agbebọn kọ lu Apọsitu Sulaimọn, wọn pa ọlọpaa ẹ mẹta ẹ

Faith Adebọla

 Bi ko pa si ti pe o rẹ iku jẹ ni, ti Ọlọrun si yọ ọ, ṣiun lo ku kawọn agbebọn kan ti wọn kọ lu ọkọ atọwọrin gbajugbaja ojiṣẹ Oluwa kan, Apọsiteli Johnson Suleiman fi ẹjẹ ọkunrin naa yi yeepẹ, nigba ti wọn bẹrẹ si i rọjo ibọn si i ni kọṣẹkọṣẹ, eeyan meje ni wọn pa nipakupa, ọlọpaa mẹta ti wọn n ṣọ ọ si wa lara wọn.

Akọlu yii waye lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa yii, nigba ti apọsiteli naa n dari bọ lati irinajo abẹwo to ṣe lọ sorileede Tanzania, bo ṣe n kọja lagbegbe Auchi, nipinlẹ Edo, ni wọn ṣe kongẹ awọn apanijaye ẹda naa, ti wọn si ṣina ibọn fun un.

Lọọya Ojiṣẹ Oluwa naa, Ọgbẹni Samuel Amune, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe “Eto ijọsin kan ni wọn ba lọ sorileede Tanzania, Ọjọruu, Wẹsidee, ni wọn pari eto naa, ti wọn si pada wale loni-in.

“Ilu Auchi ni wọn n bọ kawọn agbebọn too rẹbuu wọn lọna to gba agbegbe Sabingida wa si Warake ati Auchi, gẹrẹ ti wọn de ẹnu aala Auchi ni akọlu ọhun waye.”

Wọn ni ọsan gangan ni iṣẹlẹ ibanujẹ yii ṣẹlẹ, fun bii ọgbọn iṣẹju lawọn afẹmiṣofo fi n yinbọn mọ taja-tẹran, ṣugbọn oju ina kọ lewura n hu irun, niṣe lawọn onimọto mi-in sa lọ, nigba tawọn ọkọ kan ṣẹri pada.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Edo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o lawọn o ti i ri ẹkunrẹrẹ iroyin, awọn si ti ran ọlọpaa sibẹ lati ṣewadii ohun to ṣẹlẹ gan-an.

Leave a Reply