Awọn agbebọn kọ lu ilu Ẹda Oniyọ-Ekiti, eni kan ku

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Inu fuu, ẹdọ fuu, lawọn eeyan ilu Ẹda Oniyọ-Ekiti, nijọba ibilẹ Ilejemeje, wa lakooko ti awọn agbebọn kan ti wọn ko ti i ibi ti wọn ti wa ṣadeede ya wọ ilu naa, ti wọn si bẹrẹ si i ṣe akọlu si awọn eeyan.

Lakooko akọlu naa to waye ni kutukutu aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ko din ni eeyan meji to farapa yanna-yanna, ti wọn si ko wọn lọ sileewosan, nigba ti eeyan kan gb’ọrun lọ lojiji.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣanna ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Adewale Adeniran, sọ pe awọn ọlọpaa at’awọn ṣọja ti ṣe abẹwo siluu ọhun lati wo bi iṣẹlẹ naa ṣe lagbara to, ati lati le fopin si i. Bẹẹ lo ni wọn ti ko ọpọlọpọ awọn agbofinro lọ sibẹ

lati le pese aabo fun wọn.

“Mo fi asiko yii rọ gbogbo awọn eeyan ilu, ni pataki ju lọ, awọn ilu Ẹda Oniyọ-Ekiti, pe ki wọn lọọ ni suuru, ati pe ki wọn ma ṣe ohunkohun to le tẹ ofin l’oju. Mo ṣeleri pe awọn agbofinro ti n ṣe ohun gbogbo lati ri i pe wọn fi panpẹ ofin gbe awọn to wa nidii akọlu naa.”

Bakan naa, ninu iwe kan ti Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Taiwo Olatunbọsun, kọ lo ti rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa, pataki ju lọ, awọn eeyan ilu Ẹda Oniyọ-Ekiti.

O ni awọn agbofinro ti n ṣe ṣịṣẹ lori iṣẹlẹ naa. Ọlatubọsun ni ọrọ ija ilẹ to waye laarin ilu Ẹda Oniyọ-Ekiti ati Obo Aiyegunlẹ, nipinlẹ Kwara, lo fa akọlu naa.

Leave a Reply