Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ọkunrin mẹta kan ti wọn dihamọra ogun ni wọn padanu ẹmi wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko ti wọn wọya ija pẹlu awọn ọlọpaa niluu Ọṣunjẹla, loju-ọna Oṣogbo si Ileṣa.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i le sọ ohun pupọ nipa iṣẹlẹ ọhun lasiko ti a n koroyin yii jọ, sibẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi rẹ mulẹ.
Amọ ṣa, olugbe ilu Ọṣunjẹla kan to pe orukọ ara rẹ ni Adedimeji ṣalaye fun akọroyin wa pe marun-un ni awọn agbebọn naa, ati pe ọkada meji ni wọn gbe wọnu ilu ọhun ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ku iṣẹku mẹẹẹdogun.
O ni, “Gbogbo wa gbagbọ pe adigunjale ni wọn nitori gbogbo wọn ni wọn gbe ibọn to lagbara lọwọ. Bi ọkada wọn ṣe yọ lọọọkan bayii ni gbogbo araalu ti n sa kijokijo kaakiri.
“Bi awọn ọlọpaa ṣe ri wọn ni wọn ṣina ibọn bolẹ, bẹẹ lawọn maraarun naa si bẹrẹ si i yinbọn, ṣugbọn ko pẹ rara ti mẹta lara wọn fi dero ọrun, awọn meji to ku si sa lọ sinu igbo”
Alukoro fun ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ọṣun, Daniel Adigun, ṣalaye pe awọn agbofinro pẹlu awọn ọlọdẹ agbegbe naa ti wa ninu igbo lọwọlọwọ lati wa awọn meji ti wọn sa lọ jade.